Aye le o! Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ji pata obinrin mẹrinla l’Ayetoro

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Adeniyi Muhammed lorukọ ọmọdekunrin ti ẹ n wo yii, ọmọ ọdun  mẹindinlogun ni. Niṣe lo wọle obinrin kan, Amudalat Ọpalẹyẹ, niluu Ayetoro, lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ yii, o si ji pata iyẹn mu ko too jade nibẹ.

Muhammed pẹlu awọn pata to ji

Idaji kutu, laago mẹfa aarọ, lo wọle ji pata ọhun gẹgẹ bi Amudalat ṣe wi. O ni nibi to ti n yọ jade loun ti ri i pẹlu pata oun. Eyi lobinrin naa ṣe lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ayetoro.

Awọn ọlọpaa mu ọmọdekunrin yii, afi bi wọn ṣe de ibi to n gbe ti wọn tun ba pata awọn obinrin mi-in nibẹ, nigba ti  wọn si ka iye awọn pata naa, wọn jẹ mẹrinla, bẹẹ, gbogbo ẹ ni wọn ti wọ, ki i ṣe pata tuntun.

Nigba naa ni Muhammed ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, o ni ẹnikan lo gbe iṣẹ pata jiji ka naa foun pẹlu ileri pe oun yoo foun lowo boun ba ti n ri i ji. Iṣẹ ti bẹrẹ bayii lati mọ ẹni naa to ran an niṣẹ ọhun gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe sọ.

Ko too digba naa ṣa, CP Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn mu ọmọde yii lọ sẹka itọpinpin (SCIID)

Leave a Reply