Ayedatiwa ni yoo ṣe igbakeji Gomina Akeredolu ninu eto idibo ti yoo waye loṣu kẹwaa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu  ti forukọ ẹni to fẹẹ fi ṣe igbakeji rẹ ninu eto idibo to n bọ ṣọwọ si awọn asaaju ẹgbẹ  APC l’Abuja.

Ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹẹ gomina ọhun jẹ ka ri i gbọ pe ọmọ igbimọ ajọ to n ri si idagbasoke Niger-Delta, Ọgbẹni Lucky Ayedatiwa lo fi silẹ lasiko to lọọ gba iwe-ẹri idije rẹ ni olu-ile ẹgbẹ wọn lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọṣẹ ta a wa yii.

Ilu Ọbẹ-Nla, nijọba ibilẹ Ilajẹ, ni ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo, ni Ayedatiwa ti wa, nigba ti Gomina Akeredolu wa lati ẹkun Ariwa.

Alukoro ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, Alex Kalẹjaye, kọkọ sẹ iroyin naa, to si ni oun ko ti i ri i gbọ pe Akeredolu ti yan ẹnikẹni gẹgẹ bii igbakeji rẹ.

Gomina Akeredolu funrarẹ rẹ fidi yiyan Lucky Ayedatiwa mulẹ lalẹ ọjọ Isẹgun, Tusidee, pẹlu bo ṣe kọ orukọ ọmọ bibi Ilajẹ ọhun gadagba sori ikanni fesibuuku rẹ, bẹẹ lawọn eeyan kan ti n ki ọkunrin naa ku oriire fun bi wọn ṣe fẹẹ yan an sipo.

 

Leave a Reply