Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Ẹsọ alaabo (NSCDC) ẹka ti Patigi, nipinlẹ Kwara, ti nawọ gan Nicholas Kelechi ati Benjamin Moore, fun ẹsun pe wọn na ayederu owo (fake money).
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ni ọwọ palaba awọn ọdaran naa sẹgi, ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ, niluu Patigi, nijọba ibilẹ Patigi, nipinlẹ Kwara, lakooko ti wọn n gbiyanju lati fi owo naa ra ọja.
Agbẹnusọ ajọ (NSCDC) nipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ni ilu Ilọrin, ti ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara. Babawale ni Benjamin Moore jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ebonyi, sugbọn to n gbe ni ilu Isẹyin, nipinlẹ Ọyọ, bo se ni iyawo si Enugu, bẹẹ naa lo ni si ilu Isẹyin.
Benjamin jẹwọ pe loootọ loun n na owo to jẹ ayederu (fake) sugbọn ẹnikan lo fi le oun lọwọ ni ilu Lọkọja, ipinlẹ Kogi. O ṣàlàyé pe ilu Ibadan, nipinlẹ Ọ̀yọ́, ni baba ti awọn ra owo ayederu lọwọ rẹ ọhun wa. Igba naira (#200) lawọn fi maa n ra ẹgbẹrun kan naira (#1000) to jẹ ayederu. Ọja Yagba, nipinlẹ Kwara, lo lawọn maa n na owo naa si, ki ọwọ mọ baa tete tẹ awọn.
Ni bayii, wọn ti fi awọn ọdaran naa sọwọ si olu ileesẹ ajọ (NSCDC) nipinlẹ Kwara fun ẹkunrẹrẹ iwadii.