Faith Adebọla
A ti n gbọ iya ibeji, iya ibẹta, iya mẹrin, ṣugbọn oore kẹnkẹ to ṣọwọn ni Ọlọrun ṣe obinrin ti wọn porukọ ẹ ni Halima Cisse yii, ọmọ mẹsan-an lo bi ni ikunlẹ kan ṣoṣo, ọkunrin mẹrin, obinrin marun-un. Aṣe pe si l’Eleduwa ṣe oore ọhun, ọmọ ke, iya fọhun, gbogbo wọn lara wọn le.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, niroyin ayọ naa ṣẹlẹ, ọmọ orileede Mali niya ibẹsan-an yii, ṣugbọn orileede Morocco lo bimọ si, wọn ni ijọba orileede Mali lo ṣeto fun un lati lọọ bimọ si Morocco, nigba ti asiko ibimọ rẹ ti ku si dẹdẹ, ko baa le ri itọju to peye gba.
Ṣaaju ni ayẹwo (scan) ti wọn ṣe ti fihan pe ọmọ to wa nikun obinrin to diwọ disẹ sinu naa ju meji tabi mẹta lọ, koda ki i ṣe marun-un paapaa, ọmọ meje layẹwo lo wa nikun ẹ.
Eyi lo mu ki wọn bẹrẹ si i fobinrin naa ni itọju akanṣe, toun naa si n tẹle ilana itọju tawọn nọọsi ati dokita n fun un.
Bo tilẹ jẹ pe iṣẹ abẹ ni wọn lobinrin naa fi bi awọn ẹjẹ ọrun ọhun, wọn ni wamu wamu lẹsẹ awọn akọṣẹmọṣẹ oniṣẹ-abẹ pe, ti wọn si ṣaajo to yẹ lati ri i pe nnkan kan o ṣe iya atawọn ọmọ naa.
Minisita feto ilera lorileede Morocco, Rachid Koudhari, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni inu oun dun gidi si iroyin ayọ yii, o ni ko ṣẹlẹ ri lọsibitu eyikeyii lorileede naa pe keeyan bimọ mẹsan-an lẹẹkan naa.
Bakan naa ni Minisita orileede Mali tobinrin naa ti wa, Ọgbẹni Fanta Siby, fidi oore nla yii mulẹ, o ni ijọba orileede wọn maa pese iranwọ to yẹ fun idile t’Ọlọrun kọju si ṣe loore yii.
Ṣa, orukọ Halima Cisse ti wa lakọọlẹ ninu iwe itan awọn iṣẹlẹ gbankọgbi lagbaaye, pe ọmọ mẹsan-an lo bi ni ikunlẹ kan.