Faith Adebọla
Akolo ọlọpaa ni ọkunrin afipabanilopọ kan, Ayuba Adavo, taji si, lẹyin to ti ki obinrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan mọlẹ, to fipa ba a laṣẹpọ tan, to si gbagbe sun lọ fọnfọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, DSP Bright Edafe, lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Edafe ni ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla yii, iyẹn ọjọ Mọnde ọsẹ yii, niṣẹlẹ ọhun waye.
O niṣe lọkunrin yii pade obinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun lọna nitosi ile rẹ, wọn lo fi oogun abẹnugọngọ to wa lọwọ rẹ gba a, o tun fa ibọn pompo kan yọ si i kiyẹn ma baa pariwo, lo ba wọ ẹni ẹlẹni naa wọnu yara rẹ to wa lọna Amagiya, niluu Sapẹlẹ, o gba iro nidii ẹ, o si fipa ba a laṣepọ.
Bi Alukoro ọlọpaa ṣe wi, wọn lafurasi ọdaran yii ti muti yo kẹri ko too ṣe nnkan to ṣe yii, bo ṣe kuro lori obinrin naa lo gbagbe sun lọ fọnfọn.
Wọn ni bobinrin naa ṣe ri i pe jagunlabi ti n han-anrun lo ba yọ kẹlẹ jade ni yara rẹ, o si lọọ fẹjọ sun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Sapẹlẹ.
Wọn lawọn ọlọpaa naa lo ji i loju oorun, wọn ba ibọn ilewọ to fi halẹ mọ obinrin naa, ọta ibọn ti wọn o ti i yin, ati awọn oogun abẹnugọngọ to wa ninu yara rẹ, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e, o di akata wọn.
Wọn l’Ayuba ti n ran awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii wọn bayii, yoo si foju bale-ẹjọ tiwadii ba ti pari.