Baalẹ ọkọ ilu ti n kawọ pọnyin rojọ toun tilẹkẹ oye lọrun, eyi lẹsun buruku ti wọn fi kan an

Ọlawale Ajao, Ibadan

Baalẹ ọkọ ilu ti n kawọ pọnyin rojọ toun tilẹkẹ oye rẹ, ẹsun ti wọn fi kan olori ilu naa ni pe o lọọ ji nnkan ninu oko oloko.

Ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) ọhun, Baalẹ Ọladapọ Ọlayọde, ti i ṣe baalẹ abule

Alaropo, to wa nileto kan niluu Bọlọrunduro, lagbegbe ilu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn wọ lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, fun ẹsun ole ati iwa basejẹ, Ọlọrun nikan lo si le ba a ṣe e ti ko fi ni i fi ilẹkẹ oye rẹ ṣẹwọn lori ọrọ yii.

Oun pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ meji kan, Adio Micheal, ẹni ọdun mejidinlogoji (38), ati baba ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) kan to n jẹ Alao Adeṣina, la gbọ pe wọn lọọ ji ẹwa sóyá biǹsì ninu oko ọkunrin kan to n jẹ Ọlaniyi Arọni, ti wọn si tun ba awọn nnkan ọgbin inu oko naa jẹ.

ALAROYE gbọ pe lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindilogun (16), oṣu Kọkanla, ọdun 2023, ni wọn ti huwa ọdaran naa, eyi to sọ wọn dero atimọle awọn ọlọpaa laipẹ yii.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin, ọdun 2024 yii, lawọn ọlọpaa gbe baalẹ naa pẹlu awọn iṣọmọgbe rẹ mejeeji lọ si kootu fun ẹsun mẹta ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu ole ati iwa basejẹ.

Yatọ si soya binsi ti wọn sọ pe Baalẹ Ọlayọde atawọn eeyan rẹ ji ko ninu oko Ọgbẹni Arọni, wọn ni wọn tun ba awọn nnkan ọgbin ọkunrin naa jẹ rẹpẹtẹ.

Wọn ni nnkan ti wọn bajẹ ninu oko ọhun ko din ni miliọnu marun-un Naira (₦5m).

Ọran yii ni wọn lo la ijiya lọ labẹ ofin ọdun 2000 eyi to ṣe iwa ọdaran leewọ.

Amọ ṣa, Baalẹ atawọn ẹmẹwa re sọ pe awọn ko jẹbi eyikeyii ninu awọn ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan wọn, ile-ẹjọ si ti sun igbẹjọ naa siwaju, ki wọn le gbọ awijare olujẹjọ atawọn olupẹjọ daadaa.

Leave a Reply