O n rugbo bọ o! Ọba ti ile-ẹjọ rọ loye tun fẹẹ fawọn eeyan joye niluu Ọ̀là

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati le dena wahala ati idaluru to ṣee ṣe ko waye lopin ọsẹ yii niluu Ọla, nijọba ibilẹ Ejigbo, nipinlẹ Ọṣun, awọn ọmọ ilu naa ti kọ lẹta si kọmiṣanna ọlọpaa lati kilọ fun ọba ilu yii tile-ẹjọ ti yọ loye, Johnson Ajiboye, lati yago fun igbesẹ to fẹẹ gbe lati fi awọn eeyan kan joye niluu naa.

Lẹyin idajọ ile-ẹjọ ti wọn ti yọ ọba naa loye ni iroyin n lọ kaakiri ilu pe Ọmọọba Ajiboye tun n gbero lati fi awọn kan jẹ oye niluu naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni aafin Ọlọla.

Ninu lẹta ti Ọmọọba David Kọlawọle Ṣangoniran kọ si kọmiṣanna ọlọpaa lo ti ni igbesẹ to le da omi alaafia ilu ru ni Ajiboye fẹẹ gbe. O ni ki awọn ọlọpaa tete da si ọrọ naa lati le dena iṣekupani tabi rogbodiyan nla to le ti idi iru ayẹyẹ naa yọ nitori aibọwọ fun ofin ni.

Ṣugbọn nigba to n sọrọ lori ẹsun naa, Ajiboye sọ pe oun ṣi ni ọba ilu Ọla, nitori oun ko ti i ri iwe idajọ to yọ oun nipo ọba.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun kede orukọ awọn ọba tuntun mẹfa, ninu eyi ti Ọlọla ti ilu Ọla wa. Ṣugbọn awọn idile Olúgbòde ti David Salakọ ati Kọla Ṣangoniran ṣoju fun mori le ile-ẹjọ, wọn ni Ọmọọba Ajiboye ko lẹtọọ lati di Ọlọla, wọn ke si kootu pe ki wọn fagi le iyansipo tijọba Gomina Adeleke kede ọhun.

Bakan naa ni olori awọn afọbajẹ niluu ọhun, Dokita Fẹmi Fasanya, sọ nigba naa pe oun ko mọ si igbesẹ to sọ Ọmọọba Ajiboye di ọba, bẹẹ ni oun ko figba kankan fọwọ si i.

Ṣugbọn bi kootu ṣe mu iwe ipẹjọ lọ funjọba ipinlẹ Ọṣun ni wọn ti yara lọọ fun Ọmọọba Ajiboye ni lẹta iyansipo ni sekiteriati ijọba ni Abere, ti wọn si gbe ọpa aṣẹ fun un.

Nigba to di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, igbẹjọ waye lori ọrọ naa niwaju Onidaajọ L. O. Arọ́jọ́, ti ile-ẹjọ giga ilu Ejigbo, lori iwe ipẹjọ to ni nọmba HEJ/3/2020.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro fun awọn olupẹjọ ati olujẹjọ, ile-ẹjọ kede ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii,  gẹgẹ bii ọjọ idajọ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ọrọ naa, Onidaajọ L. O. Arọjọ, fẹsẹ taari iyansipo Ọmọọba Ajiboye gẹgẹ bii Ọlọ́là ti ilu Ọ̀là danu, o ni ko gbọdọ pe ara rẹ ni ọba mọ nibikibi.

Ile-ẹjọ paṣẹ pe ijọba ibilẹ Ejigbo ati kọmiṣanna fun ọrọ oye-jijẹ nipinlẹ Ọṣun, ko gbọdọ fun un ni lẹta iyansipo tabi gbe ọpa aṣẹ fun un, o ni ki wọn gba eyi ti wọn ba si ti fun un.

 

Leave a Reply