Ọjọ ọdun Itunu aawẹ mi Ibrahim lọọ ji mọtọ araalu kan gbe

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn alaṣẹ  ti wọn fẹsun iwa ọdaran kan wa, o n ran wọn lọwọ ninu iwadi wọn nipa ẹsun ti wọn fi kan an.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Jimeta-Mubi, nijọba ibilẹ Yola-North, nipinlẹ Adamawa, tẹ gende kan, Ọgbẹni Ibrahim Ali, pẹlu mọto ayọkẹlẹ Toyota Starlet, ti nọmba rẹ jẹ JMT 317RY, to ji lasiko ọdun Ramadan tọdun yii.

ALAROYE gbọ pe o ti pe ti ọdaran ọhun ti maa n lọ kaakiri agbegbe Jimeta-Mubi, ti yoo si ji mọto awọn araalu ọhun gbe. Lasiko tawọn araalu ọhun n ṣọdun Itunu aawẹ tọdun yii lọwọ ni Ibrahim ba tun lọọ ji mọto Toyota Starlet kan gbe, lasiko to n gbe mọto naa lọ lawọn ọlọpaa to maa n wa ni irona, ti wọn maa n yẹ ọkọ to n lọ to n bọ wo da a duro, ti ko si ri alaye gidi kan ṣe nigba ti wọn n bi i nipa mọto to wa lọwọ rẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, A.S.P Suleiman Nguroje, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa lo ni kawọn agbofinro jade sita lọpọ yanturu lasiko ayẹyẹ ọdun awọn Musulumi yii, ki wọn le pese aabo fawọn araalu. Lasiko tawọn ọlọpaa n ṣịṣẹ wọn lọwọ naa lọwọ tẹ Ibrahim pelu mọto to ji gbe.

Ọdọ awọn ọlọpaa ti Ibrahim wa lo ti jẹwọ pe loootọ, oun ji mọto naa gbe ni.

Alukoro ni awọn maa too foju Ibrahim bale-ẹjọ.

Leave a Reply