Ọkọ ofurufu agberapaa kan ti nijamba ni adugbo Ọpẹbi, niluu Eko. Gẹgẹ bi ẹni tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣe sọ, o ni niṣe lawọn kan ri i pe ọkọ ofurufu naa duro lojiji loju ọrun, lawọn wa n wo o pe ki lo mu ki ọkọ ofurufu duro soju ọrun bẹẹ. Lojiji ni ọkunrin naa ni ẹlikopita naa ja bọ sinu ile kan. Niṣe ni wọn fọ fẹnsi ile naa ti wọn fi le doola awọn to wa nibẹ.
ALAROYE gbọ pe awọn mẹta ni wọn wa ninu ọkọ ofurufu naa. Ọkunrin ni awọn mẹtẹẹta, awọn meji ti ku ninu wọn, nigba ti awọn meji to ku wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
Awọn ẹṣọ alaabo ti wa nibẹ lati mojuto iṣẹlẹ naa.