Ẹwọn ọdun mẹwaa ladajọ ju Bọlanle si ni Sokoto

Oluyinka Soyemi, Ado-EkitI

Idajọ ẹwọn ọdun mẹwaa gbako ni ọkunrin kan, Bọlanle Adefẹmiwa, gba nipinlẹ Sokoto lanaa lẹyin tile-ẹjọ sọ pe o jẹbi ẹsun gbigba owo lọna eru.

Oṣu kẹta, ọdun yii, ni ajọ to n gbogun ti iwa ikowojẹ (EFCC) sọ pe ọdaran naa ati ẹnikan to n jẹ Ṣẹgun Tinoulu, ẹni to ti sa lọ bayii, lu Dahiru Ibrahim ni jibiti ẹgbẹrun lọna igba-le-ọgbọn naira (N230,000).

Nigba ti wọn fẹjọ Bọlanle sun EFCC ni wọn wọ ọ lọ siwaju Onidaajọ Muhammad Sa’idu Sifawa, nibi ti ọkunrin naa ti ni ki wọn ṣaanu oun, loootọ loun jẹbi.

Agbẹjọro EFCC, S.H Sa’ad, fi awọn ẹri to wa nilẹ han kootu, bẹẹ lo rọ adajọ lati ṣedajọ to tọ fun ọdaran nilana ofin ipinlẹ Sokoto to ti huwa ọhun.

Ṣugbọn Amofin Shamsu A. Dauda to duro fun Bọlanle bẹbẹ fun oju aanu fun un, bẹẹ lo ni igba akọkọ ti yoo daran niyi, ati pe o ti da owo to gba ọhun pada.

Onidaajọ Sifawa yẹ ẹjọ naa wo, o si sọ ọdaran naa sẹwọn ọdun mẹwaa pẹlu anfaani lati san ẹgbẹrun lọna igba naira (N200,000) gẹgẹ bii owo itanran. 

Leave a Reply