Ipinlẹ Ekiti yoo bẹrẹ ayẹwo fawọn to fẹẹ darapọ mọ ikọ Amọtẹkun lọjọ Aje

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ijọba ipinlẹ Ekiti, nipasẹ igbimọ to n ṣakoso ikọ Amọtẹkun, yoo bẹrẹ ayẹwo igbaniwọle fawọn to fẹẹ darapọ mọ ikọ naa lati ọjọ Aje, Mọnde, to n bọ.

Ijọba kede eto ọhun lonii pẹlu alaye pe gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa l’Ekiti ni yoo ti waye, bẹrẹ lati aago mẹjọ aarọ.

Gbogbo eto nijọba loun ti n ṣe lati oṣu kẹta, ọdun yii, tileigbimọ aṣofin sọ idasilẹ Amọtẹkun di ofin ti Gomina Kayọde Fayẹmi si buwọ lu u, bẹẹ ni iforukọsilẹ ti kọkọ waye tẹlẹ lori ẹrọ ayelujara.

Ikọ Amọtẹkun nireti wa pe yoo gbogun ti iwa ijinigbe, ipaniyan atawọn iwa aburu mi-in to n da ilu laamu.

Leave a Reply