Baba Adeboye ti sọrọ: Eyi lọna abayọ si iṣoro Naijiria

Pasitọ agba ati olori ijọ Onirapada patapata, The Redeemed Christian Church of God (RCCG), Pasitọ Enoch Adeboye, ti ni ogun to n ja Naijiria kọja ti oṣelu, ati pe ọna abayọ to ni i ṣe pẹlu nnkan ti ẹmi ati adura lo le yanju ẹ.

Nile ijọba ipinlẹ Kaduna, ni Adeboye ti sọrọ yii lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun yii, lasiko to ṣabẹwọ si gomina Uba Sani.

Adeboye to wa ni ipinlẹ Kaduna latari isọji ọlọjọ meji ti wọn wa ṣe nipinlẹ naa sọ pe pẹlu bi ilu yii ṣe n kọju oniruuru iṣoro, Naijiria ṣi wa lara awọn orilẹ-ede ti Ọlọrun fi laakaye atawọn nnkan alumọọni kẹ.

O ni ọna lati fun awọn eeyan ni koriya, ki wọn ma baa sọ ireti nu, lawọn ṣe gbe isọji nla ọhun kalẹ.

Nigba to n dupẹ lọwọ gomina Sani fun bo ṣe faaye gba wọn ati atilẹyin lọlọkan-o-jọkan, paapaa ju lọ, pẹlu bo ṣe pese ọkọ ti yoo ko awọn eeyan ki isọji naa le so eeso rere lo ti sọ pe, “Mo tun ti wa ni Kaduna bayii gẹgẹ bo ṣe ti han gedegbe pe iṣoro to n ba orilẹ-ede wa finra kọja eyi to jẹ mọ oṣelu, yoo si gba ki a duro ti Ọlọrun gidigidi.

“A ti n lọ kaakiri lọna tiwa lati le kun ijọba lọwọ, lati pe Ọlọrun Alagbara ki o gba wa, nitori a nilo iranlọwọ. A n ṣe isọji lati ko awọn eeyan jọ, ki wọn le mọ pe ọla yoo daa.

“Igbagbọ wa ni pe awọn eeyan nilo iru koriya bayii nitori tawọn eeyan ba ti sọ ireti nu, ko sohun ti wọn ko le ṣe.

Awọn ọdọ n sa kuro ni Naijiria, awọn ti ko si ribi sa lọ bẹrẹ si i gbẹmi ara wọn.

“A o tubọ maa fi wọn lọkan balẹ ni pe Ọlọrun ko ni i gbagbe orilẹ-ede wa, nitori bẹẹ la ṣe ti kaakiri oriṣiiriṣii ipinlẹ, lonii yii si ree, ipinlẹ Kaduna la wa fun isọji ọlọjọ meji ti yoo waye ni papa iṣere ilu yii”.

Gomina Sani to fi idunnu rẹ han lori eto pataki ti ojiṣẹ Ọlọrun naa gbe wa si ipinlẹ rẹ dupẹ lọwọ Pasitọ Adeboye, fun ifẹ ati akitiyan rẹ lati sin ọmọniyan. O ni oun mọ pe ipa rere ni yoo ni lori awọn Kirisitẹni to wa nipinlẹ naa.

O ni ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ni wọn n sọ ireti nu, ti ẹru bi ọjọ iwaju wọn yoo ṣe ri si tun n ba wọn, gẹgẹ bi ilẹ Naijiria ṣe n la akoko to le yii kọja.

Gomina ni pẹlu iru Aarẹ to wa nipo bayii to nifẹẹ araalu, to si ṣetan lati gbe Naijiria de ibi giga, ati adura awọn eeyan bii Pasitọ Adeboye, oun mọ pe nnkan yoo ṣẹnuure fun wa laipẹ.

Leave a Reply