Eyi ni bi Cote D’Ivore ṣe gba ife-ẹyẹ bọọlu ilẹ Afrika!

Faith Adebọla

Lẹyin aadọrun-un iṣẹju ti ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti ilẹ Naijiria ti wa a ko pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Elephants ti orileede Cote D’Ivore ninu aṣakagba ifẹsẹwọnsẹ idije fun ife ẹyẹ AFCON ti ilẹ Africa, Cote D’Ivore lo bori, ti wọn si gbade agbabọọlu to peregede ju lọ!

Ami ayo meji ni Cote D’Ivore gba wọle Nigeria, nigba ti Naijiria gba ẹyọkan sawọn tiwọn.

Bo tilẹ jẹ pe lati Naijiria lo kọkọ lewaju ni nnkan bii iṣẹju mejidinlogoji ifẹsẹwọnsẹ ọhun, nigba ti William Trost-Ekong gba bọọlu sawọn Cote D’Ivore, ti ariwo ayọ si sọ lala laarin awọn ọmọ Naijiria, sibẹ awọn akẹgbẹ wọn ko kaarẹ, wọn si n ja fitafita lati da ami ayo naa pada.

Eyi ni wọn ṣe ti apa akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa fi pe, ti wọn si tun bẹrẹ ifigagbaga apa keji.

Nigba to di iṣẹju kejilelọgọta, adura Cote D’Ivore gba pẹlu bi Simon Adingra ṣe fi ẹsẹ rẹ paṣẹ fun bọọlu, ti goli Naijiria ko si ri i mu, o ta koro sinu awọn.

Ko ju bii ogun iṣẹju lọ lẹyin naa, Cote D’Ivore fọba le e, pẹlu ami ayo keji, Simon Adinga yii kan naa lo tun gba a wọle.

Gbogbo isapa Super Eagles lati dọgba pẹlu akẹgbẹ wọn yii lo ja si pabo, titi ti ifẹsẹwọnsẹ naa fi pari.

Bayii ni Cote D’Ivore fagba han Naijiria, ti wọn si gba ife ẹyẹ AFCON ti ọdun 2024 yii, fun igba kẹta.

 

Leave a Reply