Baba agbalagba tọwọ tẹ nibi to ti n hu oku olokuu l’Ondo ti foju bale-ẹjọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Baba agbalagba kan, Lasisi Isiaka, lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti wọ lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa l’Oke-Ẹda, l’Akurẹ, lori ẹsun kika ori eeyan mọ ọn lọwọ.

Aarọ ọjọ kọkanla, oṣu yii, lọwọ tẹ baba ẹni ọdun mẹtalelọgọta ọhun nibi to ti n hu oku olokuu niboji ijọ kan to wa lagbegbe Oke-Aluko, Suurulere, niluu Ondo.

Wọn ní olujẹjọ naa ti ṣẹ sofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006, niwọn igba ti ko ti ri alaye to nitumọ ṣe lori bi awọn ẹya ara oku gbígbẹ naa ṣe de ọwọ rẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ atotonu lati ọdọ agbefọba ati agbẹjọro olujẹjọ, Onidaajọ D. S. Ṣekoni pada faaye beeli baba agbalagba naa silẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (#500,000) Naira pẹlu oniduuro meji ni iye owo kan naa.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 2021, ladajọ ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply