Baba Ijẹṣa pariwo ni kootu: Ẹ ba mi tọju awọn ọmọ mi o

Faith Adebọla

Beeyan ba jẹ ori ahun, to ba ri gbajumọ oṣere tiata ilẹ wa nni, Ọlanrewaju Omiyinka, ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ni kootu ti wọn ti dajọ ẹwọn fun un l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, aanu yoo ṣe e.

Nigba ti Adajọ Oluwatoyin Taiwo ti bẹrẹ si i ka awọn ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa ati ijiya to rọ mọ ọn pẹlu ọdun ti ẹṣẹ ijiya kọọkan jẹ ni oṣere ti wọn fẹsun kan pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla kan laṣepọ naa ti bu sẹkun gbaragada ni kootu. Afi bii ọmọde lo ṣe n sunkun, to si n hu gidigidi ti ariwo ẹkun rẹ gba kootu kankan.

Niṣe ni ile-ẹjọ naa pa lọlọ, ti ọpọ si n kaaanu rẹ.

Lẹyin ti adajọ ka awọn ẹsun naa tan, to si ṣalaye idi to fi jẹbi wọn lo sinmi fun iṣẹju mẹẹẹdogun. Lẹyin naa lo gbe idajọ kalẹ pe oun ju Baba Ijẹṣa si ẹwọn ọdun mẹrindinlogun fun bi o ṣe fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla yii lo pọ. Ṣugbọn ọdun marun-un pere ni yoo lo lẹwọn nitori yoo ṣe ẹwọn naa papọ ni, bẹrẹ lati oni ti idajọ waye yii.

Bi oṣere naa ti bọ sita ni kootu lo ti bẹrẹ si i sunkun, to si n pariwo pe oun ko ṣe e, oun ko ṣe ẹsun ti wọn fi kan oun yii. Beẹ lo n pariwo pe ki wọn ba oun tọju awọn ọmọ oun. Orin aro to n kọ pe awọn yoo tun pade lọjọ mi-in lo ba ọpọ awọn eeyan ninu jẹ, ti wọn si bẹrẹ si i kaaanu rẹ. Awọn ti ko le mu ọrọ naa mọra si bu sẹkun gbaragada.

Niṣe ni awọn wọda bẹrẹ si i tu ara rẹ, ti wọn ko kọkọrọ atawọn ohun kan mi-in ti wọn ro pe o le fi ṣe ara rẹ leṣe kuro lapo rẹ.

Bẹẹ ni wọn gbe e ju sinu ọkọ agbarigo ti wọn gbe wa, ti wọn si wa a lọ si ọgba ẹwọn.

Ko ti i sẹni to le sọ boya ọkunrin naa yoo pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun.

Leave a Reply