Biṣọọbu Oyedepo fi awọn to n ni Naijiria lara gegun-un buruku

Faith Adebọla, Eko

Ilu-mọ-ọn-ka ajihinrere ati olori ijọ Living Faith Church Worldwide, tawọn eeyan mọ si ṣọọṣi Winners, Biṣọọbu David Oyedepo, ti ṣekilọ fawọn ọmọ Naijiria pe iru aṣiṣe ati aṣiyan ti wọn ṣe lasiko idibo gbogbogboo ọdun 2015, eyi to ṣokunfa bijọba Muhammadu Buhari ṣe dori aleefa, o ni wọn o gbọdọ ṣeru misiteeki bẹẹ mọ lọjọ iwaju.

Oyedepo sọrọ yii ninu iwaasu rẹ nile ijọsin ọhun lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

O ni inu n bi ohun gidi si bawọn janduku afẹmiṣofo ṣe n ṣoro bii agbọn kaakiri orileede yii, ti ọrọ naa si buru debii pe wọn n dumbu awọn Ojiṣẹ Ọlọrun bii ẹran, sibẹ tawọn ijọ dakẹ ti wọn o fiboosi bọnu.

O sọ pe ere aigbọran awọn eeyan orileede yii ni ohun to n ṣẹlẹ yii, tori oun ṣekilọ gidi ṣaaju ọdun 2015 lodi si iyansipo iṣakoso to wa lode yii, o loun sọ nigba naa pe abamọ lọrọ maa ja si.

“Ko tun gbọdọ ṣẹlẹ mọ lae, iru aṣiṣe torileede yii ṣe lọdun 2015 ko gbọdọ waye mọ titi lae. Lati dibo yan ọdaju ati alailaaanu pe ko jokoo sori aleefa iṣakoso Naijiria ko tun gbọdọ waye mọ. Igba ọtun, igba itura gbọdọ ṣẹlẹ ni lorileede yii.

Gbogbo itajẹsilẹ to n ṣẹlẹ yii, atirandiran wọn maa jiya ẹ, gbogbo igba ti ẹmi mimọ ba ni ki n sọrọ, mo mọ pe nnkan kan fẹẹ ṣẹlẹ niyẹn. Lorukọ Jesu Kristi ti mo n sin, idajọ gbọdọ bẹrẹ bayii.

Ọlọrun ẹsan ti ṣetan lati gbeja orileede yii lonii. Ẹ wo iye awọn alaimọwọ-mẹsẹ ti wọn ti da ẹmi wọn legbodo lainidii, tawọn Falani alarinkiri bẹrẹ si i mu aye su awọn eeyan, wọn si mọ pe ika lawọn n ṣe, ki i ṣe pe wọn o mọ.

Ina lo maa maa rọjo sori wọn wayi. Ẹyin ti ẹ jẹ ọmọ awọn wolii, ẹ bẹrẹ si i pe ina sori wọn, ẹ maa gbadura ki Ọlọrun rọjo ina le gbogbo wọn lori. O daju pe Ọlọrun maa gbọ. Lati asiko yii, awọn kan maa sun ti wọn o ni i ji mọ, awọn kan a ṣadeede rọ lapa rọ lẹsẹ lojiji, Ọlọrun si maa bu ifọju lu awọn mi-in ninu awọn aninilara wa. Ajalu maa de ba gbogbo wọn.”

Bẹẹ ni Biṣọọbu Oyedepo sọ ninu iwaasu rẹ.

Leave a Reply