Aderounmu Kazeem
“Bii ibo miliọnu mẹrin la ṣi fi n ju Aarẹ Trump lọ bayii, eyi to fi han wi pe awa ni yoo gbegba oroke ninu esi ibo ti wọn n ka lọwọ kaakiri ilẹ America” Joe Biden, lo ṣe bayii sọrọ nigba to sọ pe oun ti n mura lati gbakoso ipo aarẹ ilẹ America.
Nile ẹ ni Wilmington, Delaware, ni Biden ti sọrọ yii, bẹẹ lo bẹ awọn eeyan America pe ki wọn ni suuru gidi nitori oun naa mọ pe iṣọwọ ti wọn fi n ka esi ibo naa ko ya kanmọ-kanmọ to, ṣugbọn yoo dara ti gbogbo eto ba lọ bo ṣe yẹ, ti ibo tawọn eeyan di si di kika lọna to tọ pelu.
Ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democratic yii fi kun un pe, ko si aniani kankan nibẹ oun naa loun yoo jawe olubori.
Wọn ni eto ti n lọ lori bi yoo ti ṣe ka iwe apilẹkọ akọkọ ẹ fawọn eeyan America ni kete ti wọn ba ti kede pe oun ni aarẹ tuntun.
ALAROYE gbọ pe ohun to tubọ fi i lọkan balẹ ni bo ṣe na Aarẹ Trump lawọn ilu wọnyi, Arizona; Georgia, Nevada, Pennsylvania, ti Trump, ti n ni ibo to pọ tẹlẹ, ṣugbọn ti Joe Biden ti gba iwaju mọ ọn lọwọ bayii.
Ṣa o, Aarẹ Trump ti kilọ fun Biden wi pe ko ṣọra ẹ gidi ko ye pariwo kiri pe oun ti jawe olubori. Lori ikanni abẹyẹfo ẹ lo kọ ọ si wi pe, “Joe Biden to n sọ pe oun ti wọle sipo Aarẹ, tọrọ ko si ti ri bẹẹ, ohun ti emi naa le ṣe daadaa ni, emi naa le maa sọ pe mo ti wọle pada lẹẹkan si i, ṣugbọn ohun ti mo mọ ni pe ile-ẹjọ la o ti yanju ẹ nitori mi o ni i gba!”