Eeyan meji ku, mọto marundinlogoji jona nibi ijamba ina ni Kara

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Mọto tanka epo kan lo deede gbina laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu kọkanla, ni Kara, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan. Dẹrẹba to wa tanka naa ku, ọmọ ẹyin ọkọ to tẹle e naa si jona ku pẹlu,  bẹẹ ni awọn ọkọ to wa nitosi ẹ naa jona, marundinlogoji (35) lawọn ọkọ naa.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, Alukoro TRACE nipinlẹ Ogun ṣe ṣalaye, o ni awọn oṣiṣẹ oun ṣi wa nibudo iṣẹlẹ naa, awọn ko si ti i le fi gbogbo ẹnu sọ pe ijamba naa mọ niye tawọn kede yii.

Akinbiyi sọ pe boya awakọ naa n sare ju ni, boya o si n sun lori irin lasiko to n wa tanka epo naa ni, o ni awọn ko mọ. Ohun to ni o ṣaa foju han ni pe tanka naa fẹgbẹ lélẹ̀, epo inu rẹ si bẹrẹ si i danu si titi, ohun to fa ina niyẹn.

O ni mọṣuari ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ to wa mi Ṣagamu lawọn ko awọn oku meji naa lọ.

 

Leave a Reply