Bi wọn ba n tan Oyetọla, koun naa ma tan ara rẹ o jare

Ko si ohun to jẹ tuntun ninu ki awọn kan jokoo sibi kan ki wọn maa tan ẹni kan, aye la ti ba iru rẹ, bi ọrọ aye ti ri niyẹn. Eyi to buru ti ko si daa rara ni ki ẹni kan jokoo sibi kan, ko maa tan ara rẹ funra ẹ, ibanujẹ ti iyẹn maa n mu wa maa n pọ ju ti ẹni ti awọn eeyan n tan lọ. Bo tilẹ jẹ pe bi Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, fẹ, bo kọ, ọsẹ ti a wa yii ni yoo lọ, sibẹ, o si n sọ fawọn eeyan pe o da oun loju pe oun yoo gba ipo oun pada, oun yoo si maa ṣe gomina wọn lọ. Nigba ti Gomina Rotimi Akeredolu pade Oyetọla to kọkọ sọrọ yii fun un pe o da oun loju tadaa pe ko ni i pẹẹ gba ipo rẹ pada, iyẹn ni pe ko ni i pẹẹ gba ipo gomina ti awọn ẹgbẹ oṣelu mi-in gba lọwọ ẹ pada, idunnu gidi lọrọ naa yoo jẹ fun Oyetọla funra ẹ, nitori ko sẹni to wu ko fi ipo gomina silẹ, ipo teeyan ti n gbadun falala bayii, teeyan ti n paṣẹ, to si ti n jẹ gbogbo aye! Ohunkohun ti Akeredolu ri ko too sọ bẹẹ, oun lo le sọ. Ṣugbọn oun yoowu ko jẹ, o yẹ ki Oyetọla funra ẹ mọ pe iyẹn ki i ṣe ifẹ awọn ara Ọṣun, pe ti awọn ara Ọṣun ba fẹ oun ni, wọn yoo fi ibo gbe oun wọle. O dara bi eniyan ba ta ko ẹni to fẹẹ gba ipo lọwọ ẹni pẹlu gbogbo ẹsun ti eeyan ba mọ nipa rẹ ki ibo too de, eeyan le gbe e lọ sile-ẹjọ pe ko ni sabukeeti, eeyan le gbe e lọ sile-ẹjọ pe o ti jale ri, ko si ohun ti eeyan ko le ro mọ ọn lẹsẹ. Ṣugbọn ti eeyan ba waa ro gbogbo ẹjọ to le ro, ti wọn waa pada dibo tan, ti ibo naa bọ si ọwọ alatako ẹni, to jẹ pẹlu gbogbo ohun ti a ṣe, oun naa ni araalu sọ pe awọn fẹ, ti wọn si dibo fun un, ẹtọ oloṣelu to ba jẹ loootọ lo fẹran araalu yii, to si fi tiwọn ṣe, to si fẹ idagbasoke wọn, ni lati jawọ, ko foribalẹ fun ohun ti araalu fẹ, ko si maa woran. Bi tọhun ba debẹ to ba ṣe palapala, araalu yoo mọ pe awọn ṣe aṣiṣe, wọn yoo si maa wa ọna lati le e kuro nipo naa. Ti ibo mi-in ba de, o ṣee ṣe ko jẹ ẹni ti wọn fibo le danu nijọsi naa ni wọn yoo tun fibo gbe wọle, bi ọrọ awọn araalu ti ri niyẹn. Ṣugbon ki wọn dibo fun ẹni to wu wọn, ki ẹni ti wọn ko dibo fun maa waa leri kiri bi Oyetọla ti n ṣe yii pe oun yoo gba ipo naa pada, ṣebi oun naa gboju-le ọna alumọkọrọyi kan nibi kan ni. Ọna yoowu to ba si gboju-le, ọna to lodi si ohun ti awọn ara Ọṣun fẹ ni, nitori wọn o dibo to to fun un. Bi awọn ara Ọṣun ba fẹ ko maa ṣe gomina wọn lọ ni, ibo tirẹ ni yoo pọ ju, ko ni i jẹ ibo ti Adeleke. Nigba ti ibo tiẹ ko to ti Adeleke, ti wọn wa n gbe ẹjọ ko ni sabukeeti, sabukeeti ẹ ko daa, ati awọn ẹjọ mi-in dide lẹyin ti tọhun ti wọle, ṣe o waa jẹ pe awọn ara Ọṣun ko gbọ gbogbo eleyii ki wọn too dibo fun un ni. Ko si nnkan gidi kan ninu iru ẹjọ bayii, lati ko ọkan araalu soke lasan ni, o si yaayan lẹnu gan-an pe Oyetọla ti wọn n pe leeyan jẹẹjẹ ati Ọmọluabi ni wọn yoo ba nidii awọn nnkan radarada bayii! Boya Oyetọla ko mọ ni, ko si ẹni to gbagbọ pe oun lo wọle ibo akọkọ ti wọn di ni ọdun 2018, ohun ti gbogbo araalu mọ ni pe wọn da ọgbọn ojooro si i ni, Aarẹ Muhammadu Buhari funra ẹ si sọ pe ọgbọn agba lawọn lo si ibo Ọṣun, bi ko jẹ bẹẹ, ẹni awọn iba fidi-rẹmi. To ba waa jẹ pẹlu gbogbo iṣẹ ti Oyetọla ṣe l’Ọṣun nigba to fi n ṣe gomina yii, ti awọn eeyan ko ba fi tun dibo fun un debii pe alatako rẹ ko ni i le sun mọ ọn rara, a jẹ pe kinni kan wa ti awọn eeyan Ọṣun yii fẹ fun ara wọn ni, wọn ko si ro pe awọn le ri i gba lọwọ Oyetọla. Ewo waa ni keeyan maa fi tipatipa ti ara rẹ mọ awọn ti wọn lawọn ko fẹ ẹ lọrun, oore ki lo wa ninu keeyan fi tipatipa jọba le awọn eeyan lori! Nitori kin ni? Awọn yoowu ti wọn ba n tan Oyetọla pe yoo ri ipo rẹ gba, nitori pe o ṣi wa nibẹ ni wọn ṣe n sọ ọrọ didun fun un o, nigba to ba kuro tan, oun naa yoo ri i bi aye ti n yinmu si ni. Ko si ohun ti yoo wu gbogbo awọn ti wọn yi i ka ju ko wa nipo gomina lọ, bẹẹ ni eyi ki i ṣe nitori wọn fẹran awọn ara Ọṣun tabi wọn fẹran oun paapaa, nitori ohun to wa lọdọ kaluku to n pọn la lọwọ ni. Bo ba kuro tan, loju rẹ ni ọpọlọpọ awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ bayii yoo bẹ mọ ẹni to gba ipo lọwọ rẹ. Gbogbo aṣiri to si ni lọwọ pe oun yoo fi ba tọhun ja, awọn ọrẹ rẹ atijọ yii ni yoo tu u fun un, ki wọn le tun maa ri tiwọn jẹ lọdọ ẹni to ṣẹṣẹ de. Nitori bẹẹ, ki Oyetọla yee daamu ara ẹ, ko fi ara ẹ lọkan balẹ, ko kuro ni Ọṣun pẹlu iyi ati ẹyẹ. Gbogbo eyi to n ba kiri yii ko le ran an lọwọ, abuku nikan ni yoo gbeyin rẹ, ko si dara ki abuku kan ẹni to ti niyi tẹlẹ, nitori ẹ ni Oyetọla ko ṣe gbọdọ tẹle ọrọ awọn ẹlẹtan, ko ṣe ohun tawọn ara Ọṣun yoo fi maa nifẹe rẹ titi aye ni.

Leave a Reply