Awọn aṣofin Eko sunkun gidigidi nibi eto idagbere fun ọkan ninu wọn to ku si Jos

Faith Adebọla, Eko

 Yoruba bọ, wọn ni lọjọ a ku la a dere, eeyan o sunwọn laaye, ko sẹni ti yoo wa nileegbimọ aṣofin Eko l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla yii, lasiko ijokoo akanṣe ti wọn fi ṣeranti ọkan lara wọn to doloogbe lojiji, Ọnarebu Abdul-Subor Ọlayiwọla Ọlawale, tawọn eeyan mọ si ‘O mi titi,’ ti tọhun ko ni i kaaanu awọn ẹlẹgbẹ rẹ yii, niṣe ni wọn n wa ẹkun mu bii ọmọdẹ, ti wọn si n fi bi iku ọkunrin naa ṣe ka wọn lara to han.

Oloogbe yii ati ọpọ lara awọn aṣofin ẹlẹgbẹ rẹ ọhun ni wọn jọ wa papọ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu yii, iyẹn ọjọ meji ṣaaju iku rẹ, nibi ayẹyẹ akanṣe kan ti wọn pe ni ‘sọpurais baidee pati’ (surprise birthday party) ti wọn ṣe lati fi ṣapọnle olori ileegbimọ aṣofin ọhun, Ọnarebu Mudaṣiru Ajayi Ọbasa, fun ti ayẹyẹ ọjọọbi aadọta ọdun rẹ. Otẹẹli kan ni Victoria Island, l’Erekuṣu Eko lọhun-un, ni leto naa ti waye, oloogbe yii si wa nibẹ, wọn jọ jẹ, wọn jọ mu, wọn jọ ṣariya titi dalẹ patapata ni, ki wọn too gbera lọjọ keji lati lọọ wọ baaluu ti yoo gbe wọn re’lu Jos, nipinlẹ Plateau, nibi ti wọn ti fẹẹ ṣide eto ipolongo ibo aarẹ fun oludije ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.

Bo ṣe ku diẹ ki wọn pari eto pọpọ-ṣinṣin ọhun lọjọ Tusidee ọhun, ni iku alumutu yọ kẹlẹ wọ aarin wọn, ojiji lọkunrin ti wọn lo n ta kebekebe naa ṣubu lulẹ, nigba ti wọn yoo si fi ṣaajo ẹ, ti wọn du u dele-iwosan, leyii ti ko ju iṣẹju diẹ lọ, akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin.

Ọjọ keji ni wọn gbe oku rẹ pada s’Ekoo, ti wọn si sin in nilana ẹsin Musulumi si itẹkuu Ebony Vault, to wa n’Ikoyi.

Ki wọn too yọ orukọ aṣofin naa kuro lori aga to maa n jokoo si, ti wọn si yọ ẹsẹ rẹ lẹgbẹ, gẹgẹ bii aṣa wọn tiru iṣẹlẹ bẹẹ ba ṣẹlẹ, awọn aṣofin naa kọkọ duro idakẹjẹẹ oniṣẹẹju-kan fun oloogbe yii, lẹyin naa ni wọn parọwa si Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, lati ṣeranwọ iṣẹ ati ẹkọ-ọfẹ fawọn ọmọ meji ti Ọlayiwọla fi saye lọ, wọn l’adiẹ ki i ku ka da ẹyin ẹ nu.

Lẹyin eyi ni ọkọọkan wọn sọrọ lori igbe aye aṣofin yii, ọrọ ṣe’ni wo, ka le mọ ẹni to fẹ’ni, pẹlu ikoro oju ni kaluku wọn fi sọrọ, ọpọ lo gbiyanju lati ma ṣe b’ọkunrin jẹ, ṣugbọn nigba to ya, wọn ko le mu un mọra mọ, wọn bu sẹkun bi wọn ṣe n royin ajọṣe wọn pẹlu Oloogbe Ọlayiwọla, ati bi iku rẹ ṣe jẹ agbọ-sọgba-nu fun wọn to.

Olori ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ nile aṣofin naa, Ọnarebu Sanai Agunbiade ni angẹli kan teeyan o fura si ni aṣofin to pẹyinda yii. “Bo ṣe ku diẹ ka gbera irinajo wa lọ si Jos, ẹfọri kan n ṣe mi, mi o tiẹ sọ fun un, amọ o kan fura pe nnkan kan ti n ṣe mi, bo si ṣe mọ bayii, gbogbo aajo to yẹ lo ṣe fun mi, ko sinmi titi tara fi tu mi. O tiẹ n sọ fẹnikan lori foonu pe kilẹ ọjọ keji too mọ, oun maa tete pada s’Ekoo ni toun ta a ba ti pari eto ta n lọọ ṣe lọhun-un. Nigba ta a si debẹ naa, a jọ wa papọ ni, a jọ nlọ ta a jọ n bọ ni, a jọ n ṣe gbogbo nnkan ni, ko tiẹ si apẹẹrẹ ojojo tabi aarẹ kan bayii lara ẹ, eeyan o le ronu iku si i rara,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Ọnarebu Victor Akande ni tiẹ sọ pe, “emi ni mo pe ‘O mi ti ti’ lori aago pe o ti ya o, ko jẹ ka pade ni ẹẹpọọtu, emi ati Ọnarebu Jude Idimogu la jọ wa nigba yẹn. Mi o le gbagbe bo ṣe n ran mi leti pe ki n ma gbagbe lati mu awọn oogun mi dani o, to tun n fi ibi ti ma a ti ra omi han mi. Igba ti ọkan ninu wa ni iṣoro lati gba iwe aṣẹ ta a maa fi wọ baaluu, ti wọn o fun un ni boarding pass, kia lo ti lọọ ṣeranwọ, to si ba ẹni yẹn gba a,” bẹẹ l’Akande sọ tomije tomije.

Lẹyin eyi lo bẹnu atẹ awọn gbọyii-sọyii ẹda kan ti wọn n gbe irọ kiri nipa aṣofin naa, o loun gbọ iroyin ofege kan nibi ti wọn ti fẹsun kan oloogbe naa pe onigbese ni, pe o jẹ alaga ijọba ibilẹ kan lowo rẹpẹtẹ, o ni irọ to jinna soootọ ni o.

Ọrọ ti Ọnarebu Rotimi Olowo sọ nipa oloogbe naa tun mu kawọn eeyan tubọ sori kodo, ti wọn si mi kanlẹ. Lẹyin to ti sọ bi Ọlayiwọla ṣe nifẹẹ aiṣẹtan soun atawọn mọlẹbi oun to, o ni “awọn obi oloogbe yii tete ku, o si fẹrẹ maa gbọnju mọ wọn daadaa. Sibẹ, o tiraka lọwọ ara ẹ, o pebi mọnu lati kawe, titi to fi laluyọ. O n palẹmọ ayẹyẹ ifọmọfọkọ to fẹẹ ṣe fọmọ ẹ loṣu Disẹmba ni iku paju ẹ de yii. Mo ranti pe inu baaluu la wa ta a gbọ ti iku agba-ọjẹ oṣelu-binrin ẹgbẹ APC kan tawọn eeyan mọ si Iya Oniyan, l’Ekoo. Ọlayiwọla wa lara awọn to kọ haa, o loun maa tete pada ta a ba ti ṣetan ni Jos, tori oun gbọdọ de ọdọ awọn mọlẹbi naa lati lọọ ba wọn daro, laimọ pe oun alara to n sọrọ gan-an, wakati diẹ lo ku fun un loke eepẹ.”

Bayii ni ọkọọkan awọn aṣofin naa sọ ero ati ajọṣe wọn pẹlu oloogbe ọhun. Bakan naa ni wọn dupẹ gidigidi lọwọ Gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong, to jẹ alaga eto ipolongo aarẹ ẹgbẹ APC fun aduroti ati ifọmọniyan-ṣe rẹ latigba tiṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ. Bakan naa ni wọn kan saara si olori wọn, Mudaṣiru Ọbasa, ati Aṣiwaju Bọla Tinubu, Gomina Babajide Sanwo-Olu, Igbakeji re, Ọbafẹmi Hamzat, atawọn iyawo wọn, pẹlu ọgọọrọ eeyan to dide iranwọ nigba tiṣẹlẹ ibanujẹ naa waye, wọn lẹni to ṣoju o to ẹni to ṣẹyin de ni.

Wọn waa tẹwọ adura pe k’Ọlọrun fi eyi ṣopin iku ojiji laarin awọn, ko si mu itunu ati itura ba awọn mọlẹbi Oloogbe Ọlayiwọla Abdul-Subor to rewalẹ asa lojiji.

Leave a Reply