Faith Adebọla
Orin bi apa o ba ṣe e ṣan, niṣe la a ka a leri, okele gbigbẹ ati alaafia si san ju ẹran abọpa ati ija lọ, lo gbẹnu iyaale ile kan, Mariam Wasiu, nigba to n rawọ ẹbẹ sawọn adajọ kootu kọkọ-kọkọ to wọ ọkọ rẹ, Ibrahim Wasiu, lọ pe ki wọn tu igbeyawo awọn ka, oun o ṣe mọ. O ni ọkunrin naa ti n dunkooko mọ ẹmi oun, oun o si ti i ṣetan iku bayii.
Kootu kọkọ-kọkọ Grade A, to fikalẹ sagbegbe Mapo, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, lọrọ yii ti waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii.
Olupẹjọ naa, Mariam, rọjọ niwaju awọn adajọ pe titi dasiko yii ni nnkan to yi kadara ọkọ oun pada lati eeyan pẹlẹ, to nifẹẹ, to si n ṣikẹ obinrin, toun mọ ọn si nigba toun kọkọ fẹ ẹ si aluni ati ẹhanna to waa ya lasiko yii ṣi n ru oun loju.
O ni niṣe lọkọ oun maa n lu oun bii ẹni lu baara lori ọrọ ti ko to nnkan, ki i si ṣe pe yoo lu oun bẹẹ lasan, o digba ti ẹjẹ ba jade lara oun, to ri i pe oun fara ṣeṣe ko too fi oun oun silẹ.
O loun to tubọ mu koun pinnu pe afi koun pin gaari pẹlu abẹṣẹẹ-ku-bii-ojo toun n pe lọkọ yii ni bo ṣe tun maa n dẹ awọn ọmọ toun bi fun un soun, titi kan ọmọọdọ tawọn gba, wọn maa n dawọ-jọ lu oun ni, ati pe lọjọ kan tawọn n ja, niṣe lọkọ oun n leri pọn-ọn-ran-pọn pe o digba toun ba ri i pe oun lu oun pa patapata koun too jawọ, eyi si dẹruba oun pupọ, tori kọrọ aye ya ju kọrọ ọrun lọ.
“Okoowo ati kara-kata lọkọ mi n ṣe nigba ti mo pade ẹ, o si nifẹẹ mi bii oju nigba yẹn, eyi lo jẹ ki n loyun fun un, ti mo si ko wọle ẹ, mo si gbadun lawọn ọdun ta a kọkọ fẹra yẹn, afi bi wọn ṣe yi pada lojiji, tẹni to n kẹ mi loju nimu tẹlẹ waa di alalupamokuu.
To ba n lu mi, ko si bi mo ṣe le kigbe to, o digba to ba gbẹjẹ lara mi ko too fi mi silẹ, ẹ wo gbogbo awọn apa to wa lara mi yii (o fi ara rẹ han awọn adajọ), ko seyii ti mo gbe wọ ile ẹ nibẹ, oju ọgbẹ to da si mi lara nigba ta a n ja ni.
Bakan naa lo tun maa n febi pa emi atawọn ọmọ, ọjọ to ba wu u lo n fun wa lowo, ọpọ ọjọ tabi ọsẹ ni ko tiẹ ni i ṣe bii pe oun ri wa rara, ko bikita fun wa mọ.
Ọmọ mẹrin ni mo bi fun un, mi o si le fawọn ọmọ mi silẹ sakata ẹ, ẹ ṣaa ba mi pa a laṣẹ lati gbọ bukaata awọn ọmọ ẹ.”
Ni gbogbo asiko ti igbẹjọ yii fi waye, olujẹjọ naa ko si ni kootu, bẹẹ ni ko yọju pẹlu bi wọn ṣe fiwe ipẹjọ jiṣẹ fun un leralera to.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Abilekọ S. M. Akintayọ ni ọrọ tọkọ-taya naa ko ṣẹṣẹ ni pe awọn n tu igbeyawo kankan kan ninu, tori ko si igbeyawo gidi laarin wọn latilẹ, wọn ni ko si ayẹyẹ mọ-mi-n-mọ-ọ kan, bẹẹ ni eto igbeyawo ibilẹ ko waye, ọkunrin naa ko si sanwo-ori iyawo kan.
Latari eyi, adajọ paṣẹ pe kawọn ọmọ meji ti wọn ti dagba wa lakata baba wọn, kawọn meji tọjọ-ori wọn ṣi kere wa lakata iya wọn, amọ baba wọn ni ko maa gbọ bukaata atijẹ atimu awọn ọmọ mẹrẹẹrin, ko si gbọdọ kuna lati sanwo ileewe wọn.
Ile-ẹjọ naa was paṣẹ pe ki tọkọ-taya yii pin gaari, ki kaluku maa lọ lọtọọtọ.