Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Bolu Ojo, ti dero kootu Majisreeti to wa niluu Ado-Ekiti lori pe o fọ ile purofẹsọ kan, o si ji awọn ẹru ko kọwọ too tẹ ẹ.
Inspẹkitọ Oriyọmi Akinwale sọ fun kootu naa pe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu to kọja, ni Bolu ati ẹnikan to ti fẹsẹ fẹ ẹ bayii huwa ọhun nile Purofẹsọ Ọlọfintoye Thomas to wa lagbegbe Ekute, niluu Ado-Ekiti.
Oriyọmi ni aago mẹwaa aarọ lawọn eeyan naa gbimọ pọ ṣiṣẹ laabi ọhun, bẹẹ ni wọn ji awọn ẹru towo wọn le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N524,000), eyi ti gbogbo ẹ jẹ dukia Purofẹsọ Ọlọfintoye.
Akọsilẹ kootu naa fi han pe Bolu ji faanu meji towo wọn jẹ ẹgbẹrun lọna aadọta naira (N50,000), igi bẹẹdi towo ẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọjọ naira (N160,000), ìdì waya meji towo wọn to ẹgbẹrun lọna ọgọjọ naira (N160,000), ìdì waya mẹrin mi-in towo wọn to ẹgbẹrun mẹrinlelaaadọta naira (N54,000), sitoofu meji towo wọn to ẹgbẹrun lọna ogun naira(N20,000), awọn pọọtu towo wọn to ẹgbẹrun lọna ọgọta naira(N60,000) ati faanu orule meji towo wọn to ẹgbẹrun lọna ogun naira (N20,000).
Nigba tọrọ kan Bolu, olujẹjọ naa ni oun ko jẹbi, eyi to jẹ ki Amofin Gbenga Ariyibi to duro fun un rọ kootu naa lati fun un ni beeli lọna irọrun pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ.
Lẹyin agbeyẹwo iwe ipẹjọ, Majisreeti Adefunkẹ Anoma faaye beeli ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (N100,000) ati oniduuro meji ti wọn n gbe niluu Ado-Ekiti ti wọn si ni ojulowo adirẹẹsi.
Igbẹjọ yoo tẹsiwaju lọjọ kejilelogun, oṣu to n bọ.