Buhari ti wọn lo ti ku: Ọbasanjọ ṣalaye ọrọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko seni to le ba awọn eeyan kan sọ ọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti wọn dibo fun lọdun 2015 lo wa lori aleefa lasiko yii ti wọn yoo gbagbọ, ohun ti wọn gbagbọ ni pe Buhari ti ku, wọn ti sin in tipẹ siluu oyinbo to ku si, ati pe ẹnikan to n jẹ Jubril lati Sudan lo ti n ṣe olori wa bọ lati ọdun bii mẹrin ti Buhari ti ku naa.

Ọrọ yii ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, aarẹ igba kan ni Naijiria, ṣalaye nipa ẹ ninu fidio kan lori ayelujara. Ọbasanjọ sọ pe nnkan abuku gbaa ni pe awọn eeyan kan n gba iru iroyin bii eyi gbọ.

O ni ara ibajẹ to wa lori ẹka ayelujara niyẹn, nitori iroyin ẹlẹjẹ gbaa ni. Buhari ko ku, oun naa lo wa l’Abuja to n ṣejọba.

Ọbasanjọ sọ pe,  “Eeyan pataki kan lawujọ wa lo waa ba mi to n sọ fun mi pe Buhari kọ lo n ṣejọba, o sọ fun mi pe o maa ti kari aye gan-an, pe gbogbo eeyan lo ti mọ pe Buhari ti ku tipẹ.

”Mo beere lọwọ ẹ pe ṣe o gba awọn to n sọ bẹẹ gbọ, o ni bo ṣe wa lori ayelujara niyẹn. Mo ni ṣe Buhari yoo ku, a o si ni i mọ pe Buhari ti ku, wọn aa si gbe ẹnikan wa lati Sudan pe oun ni Buhari. O taayan labuku kọja aala.

“ Nitori pe o wa lori ayelujara lawọn eeyan kan ṣe n gba a gbọ. Ẹrọ ayelujara daa, ṣugbọn awọn eeyan maa n lo lọna aitọ nigba mi-in. A gbọdọ kọ awọn ọmọ wa nipa ewu to wa ninu lilo ẹrọ ayelujara.’’

Bẹẹ l’Ọbasanjọ wi.

 

Leave a Reply