Faith Adebọla
Olori orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti yan ọga agba tuntun fun ileeṣẹ awọn ọdọ to n sin ilẹ baba wọn lẹyin ẹkọ wọn, National Youth Service Corps, Ọgagun Mohammed Fada, lati ipinlẹ Yobe, ni wọn yan.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un yii, ni iyansipo naa waye, Fada yoo gba iṣẹ lọwọ Ọgagun Shuaibu Ibrahim to ti wa nipo naa lati ọdun 2019.
Atẹjade kan lati ileeṣẹ Aarẹ sọ pe Aarẹ Buhari ti fọwọ si iyansipo Mohammed Fada, gẹgẹ bii ọga agba tuntun fun ileeṣe awọn agunbanirọ.
Atẹjade naa sọ pe Ọga agba ajọ naa tẹlẹ, Ibrahim, ati ẹni tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan yii ti fikun lukun, wọn si ti jọ sọrọ lori bi wọn ṣe maa fa iṣẹ le ara wọn lọwọ.
Ọmọ bibi ilu Nasarawa, nipinlẹ Nasarawa, ni Ibrahim to kuro nipo naa, wọn lo fẹẹ lọ fun idalẹkọọ pataki kan tawọn ọgagun maa n lọ.