Buratai ti kọwe sijọba Olominira Benin, o ni ki wọn yọnda Sunday Igboho fawọn

Faith Adebọla

Ọga ologun ilẹ wa tẹlẹ to tun jẹ aṣoju Naijiria ni orileede Olominira Benin, Turkur Buratai ti kọwe si orileede Benin bayii pe ki wọn fa Sunday Igboho le awọn lọwọ ki awọn maa mu un pada b ọ si ilẹ Naijiria.

Ọjọruu, Wẹsidee, la gbọ pe o gbe iwe lọ sọdọ awọn alaṣẹ orileede naa pe ki wọn jọwọ jare, yonda ajijagbara ọmọ Yoruba yii, Sunday Igboho fawọn.

Awọn ẹsun ti Buratai ka si Sunday ninu lẹta to kọ naa gẹgẹ bi wọn ṣe yọ sọ fun ALAROYE ni pe ọkunrin naa sọ pe arufin ni ajijagbara ọmọ Yoruba naa, o ni apaayan ni, adaluru ni, o si n da wahala silẹ kaakiri orileede.

Buratai ni afi dandan ki ajijagbara yii waa jẹ awọn ẹjọ yii ni Naijiria.

Ṣugbọn awọn agbẹjọro ti akọroyin wa ba sọrọ labẹlẹ sọ pe ibeere ti ọkunrin naa n beere ko ni i ṣee ṣe.

O ṣalaye pe niwọn igba to jẹ pe ẹsun to ni i ṣe pẹlu ọrọ oṣelu ni Sunday Igboho tori rẹ kuro nile, wọn ko ni i fa a le ijọba Naijiria lọwọ. Ọkunrin naa sọ pe iru iṣẹlẹ yii kan ti wa nilẹ tẹlẹ ti wọn yoo fi ṣe awokọṣe. Iyẹn naa ni ti Ọjọgbọn Banjọ to n gbe orileede Amẹrika nigba naa ti wọn fẹsun kan ni aye ijọba Abacha pe o ko ohun eelo ijagun wọ Naijiria, to si sa lọ si orileede Benin nigba ti ijọba Abacha fẹẹ mu.

Ijọba Abacha kọwe sijọba Benin nigba naa pe ki wọn fi ọkunrin yii ranṣẹ sawọn, ṣugbọn ijọba ibẹ ko da wọn lohun.

Nipa bayii, ko daju rara pe wọn yoo gbe Sunday Igboho pada si Naijiria.

 

Leave a Reply