Busọla foju bale-ẹjọ, miliọnu meje owo ileewe to n ba ṣiṣẹ lo poora mọ ọn lọwọ

Faith Adebọla, Eko

 Abilekọ ẹni ogoji ọdun kan, Oluwabusọla Oluwatosin, ti fara han nile-ẹjọ Majisreeti Ikẹja, nipinlẹ Eko, latari ẹsun pe o lu jibiti, o ṣe miliọnu meje owo ileewe to n ba ṣiṣẹ mọkumọku.

Owurọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni awọn agbofinro wọ obinrin naa de kootu, wọn si ka awọn ẹsun ti wọn fi kan an si i leti niwaju adajọ.

Ninu alaye ti Agbefọba, ASP Benson Emuerchi, ṣe nipa ẹsun ọhun, o ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileewe aladaani Early Beginner School, to wa lagbegbe Ifakọ Ijaye, nipinlẹ Eko, ni Oluwabusọla, o si ti ṣe diẹ to ti n ba wọn ṣiṣẹ nileewe naa.

Wọn lafurasi ọdaran yii lo n ba wọn bojuto iṣiro owo nileewe ọhun, ṣugbọn laarin oṣu karun-un to kọja, aṣiri tu pe obinrin naa ti lọọ ṣi akaunti mi-in si banki lorukọ ileewe ọhun, akaunti ọhun to jọra pẹlu eyi ti ileewe naa n lo latilẹ ni wọn lo fi rọ owo jade ninu asuwọn banki ileewe naa, wọn tun lo ṣe ayederu awọn iwe kan titi kan risiiti (receipt) ti wọn n ja fawọn to sanwo wọle, ko le ri jibiti ọhun lu daadaa.

Nigba ti awo ya, ti wọn ṣiro owo to sọnu mọ ọn lọwọ, miliọnu meje o din ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#6.95million) lo ti dawati. Eyi lo mu ki wọn fi pampẹ ofin gbe e, to si fi dero kootu.

Lara ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ ni ṣiṣẹ ayederu iwe, lilu jibiti ati ole jija, eyi ti wọn lo ta ko isọri irinwo le mọkanla (411), ojilelọọọdunrun o din mẹta (337) ati ọrinlerugba o le meje (287) iwe ofin iwa ọdaran ti ọdun 2015 nipinlẹ Eko.

Nigba to kan afurasi naa lati sọrọ, Oluwabusọla loun ko jẹbi. Eyi lo mu Adajọ J. A. Ayegun sun igbẹjọ rẹ si ọjọ ki-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, o si yọnda beeli fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira, oniduuro meji ni iye owo kan naa, ti wọn si ni dukia to jọju layiika kootu ọhun, ki ọkan ninu wọn si jẹ oṣiṣẹ ijọba onipo giga.

Leave a Reply