Faith Adebọla, Eko
Ṣẹ ẹ ranti obinrin alafẹ ilu Eko, Chidinma Pearl Ogbulu, tọrọ pati rẹ ja ranyin lori ẹrọ ayelajara lọsẹ mẹta sẹyin, latari bo ṣe ha bẹntiroolu fawọn alejo to waa ba a ṣayẹyẹ iwuye to ṣẹṣẹ jẹ naa.
Ile-ẹjọ Majisreeti alagbeeka to wa niluu Oṣodi, nibi tobinrin arẹwa yii ti n kawọ pọnyin rojọ, ti pari igbẹjọ rẹ, ẹwọn ọdun meji ati oṣu mẹta ni wọn ni ko lọọ fi jura fun ẹṣẹ ti wọn lo da ọhun.
Ẹsun mẹta ọtọọtọ ni wọn ka si obinrin naa lẹsẹ lasiko igbẹjọ rẹ, wọn lo ṣokoowo titọju bẹntiroolu pamọ lai gbaṣẹ, wọn ni bo ṣe ha bẹntiroolu naa fawọn eeyan le ṣepalara fun ọmọlakeji, ati pe iwa to le pa alaafia ati aabo ilu lara lohun to ṣe.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Kẹhinde Ogundare ni awọn ẹri to wa niwaju kootu naa ko ni ariyanjiyan ninu rara, o han kedere pe afurasi ọdaran yii jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Wọn ni ẹṣẹ to da naa lodi si isọri kẹẹẹdọgbọn (25), iṣọri kejidinlaaadọsan (168) ati isọri ojilerugba le mẹrin (244) iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Eko, ti ọdun 2015, o si tun ṣẹ lodi si isọri karundinlaaadọwaa (195) abala keji, iwe ofin aabo ati itọju ayika nipinlẹ Eko (Environmental Management Protection Law of Lagos State), tọdun 2017.
Adajọ ni ki obinrin to n ṣiṣẹ afẹwa-ṣoge ọhun lọọ sẹwọn ọdun mẹta lori ẹsun akọkọ, tabi ko san faini ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (N15,000), ẹwọn ọdun kọọkan ni yoo lọ lori ẹsun keji ati ẹkẹta, tabi ko san owo-itanran ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000) lori ọkọọkan.
Adajọ ni ẹẹkan naa ni yoo ṣẹwọn ọhun papọ ti ko ba rowo itanran san, eyi tumọ si pe ọdun kan pere ni yoo lo lẹwọn.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ karun-un, ọṣu Kẹta, ọdun yii, lobinrin naa ṣe pati to dọran si i lọrun yii ni gbọgan ayẹyẹ Havillah, l’Erekuṣu Eko, to si ha kẹẹgi ti jala marun-un (5 litres) epo bẹntiroolu wa ninu rẹ, pẹlu fọto rẹ lara kẹẹgi ọhun, fawọn alejo rẹ.
Tori pe o ṣe ohun tẹnikan o ṣe ri lariwo fi gbode lori ẹrọ ayelujara lẹyin pati naa, eyi lo mu kawọn ọlọpaa mu un, ijọba Eko si da a lẹbi fun iwa aibikita to hu. Ọjọ kẹrinla, oṣu yii, ni wọn kọkọ foju Chidinma bale-ẹjọ.