Dapọ Abiọdun ṣabẹwo si Yewa, o ṣeleri iranwọ fawọn tijamba kan

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keji, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ṣabẹwo si Ọja-Ọdan, ni Yewa, o ni ijọba yoo ran awọn tile wọn jona lọwọ, awọn yoo sanwo ọsibitu awọn to n gbatọju pẹlu.

Ṣaaju ileri yii ni gomina ti kọkọ ba awọn to padanu eeyan wọn ninu ikọlu to waye lawọn ilu bii Orile-Igboro, Owode-Ketu, Egua, Agbọn Ojodu, Aṣa ati bẹẹ bẹẹ lọ kẹdun. O bu ẹnu atẹ lu iwa ipaniyan ati biba dukia jẹ to n ṣẹlẹ nilẹ Yewa.

Ikorita Ọja-Ọdan ni Gomina Abiọdun atawọn ikọ rẹ ti ṣalaye fawọn eeyan Yewa pe ikọ alaabo ti yoo ni ṣọja ninu, ti ọlọpaa yoo wa nibẹ pẹlu awọn Sifu Difẹnsi atawọn mi-in yoo gunlẹ si Yewa lọsẹ yii.

O ni bi wọn ko ba de lọjọ Iṣẹgun, nigba ti yoo ba fi di Ọjọruu, awọn ikọ alaabo ti wọn yoo tẹ ẹ pa sawọn agbegbe yii yoo gunlẹ.

Bakan naa lo sọ pe awọn gomina marun-un lati apa Ariwa orilẹ-ede yii n bọ l’Abẹokuta lati waa ba oun ṣepade lori ohun to n ṣẹlẹ yii, awọn yoo jọ sọ asọye pọ nipa bi nnkan yoo ṣe pada si daadaa.

Olu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle, lo gba Gomina Abiọdun lalejo lọjọ naa, pẹlu Eselu ti Iselu, Ọba Akintunde Akinyẹmi, bẹẹ lo ṣoju awọn baalẹ kọọkan pẹlu, ti gbogbo wọn n sọ pe kijọba tete ran awọn lọwọ, kawọn to ti sa kuro lawọn ilu yii le pada sile wọn.

Leave a Reply