Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti i ṣe ọgbọnjọ, oṣu kọkanla, ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, gbe aba iṣuna ọdun to n bọ ti ipinlẹ wọn yoo lo lọ fawọn aṣofin. Iṣuna isọdọtun( Budget of restoration) ni wọn pe e. Ọọdunrun biliọnu aabọ ati mẹrinlelaaadọrin naira ni (350.74bn)
Nigba to n ṣe atupalẹ aba naa l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta, Gomina Abiọdun ṣalaye pe aadoje biliọnu ( 170b) yoo ba awọn ojulowo iṣẹ lọ, biliọnu marundinlọgọrin( 75b) yoo wa fun owo iṣẹ sisan.
Biliọnu mọkanlelaaadọta (51bn) yoo wa fun awọn iṣẹ tijọba n ri si ( Overhead expenses). Biliọnu mejidinlọgbọn (28bn) ni wọn yoo fi maa yanju awọn gbese to ba wa nilẹ.
Biliọnu mejilelọgọrin( 82 bn) lowo ti wọn ya sọtọ fun nnkan amayedẹrun, biliọnu mẹrindinlaaadọrun-un( 86bn) lowo igbaye-gbadun, biliọnu mẹrindinlọgọta (56bn) lo wa fun eto ẹkọ.
Lori eto ọgbin, biliọnu mẹẹẹdogun (15bn) lowo ti wọn ya sọtọ, eto idajọ, aabo, owo ifẹyinti ati ajẹmọnu yoo gba ọgọrun-un kan biliọnu ati mẹfa (106) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gomina sọ fawọn eeyan nile naa pe afojusun ijọba ni lati mu gbogbo aba yii ṣẹ, eyi yoo si ṣee ṣe pẹlu atilẹyin Ọlọrun atawọn eeyan to kan gbọngbọn.
Olori ileegbimọ aṣofin Ogun, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, o dupẹ lọwọ Gomina Abiọdun fun alakalẹ eto iṣuna naa, bẹẹ lo ṣeleri atilẹyin funjọba yii gẹgẹ bo ṣe wa latẹyinwa.
Diẹ ninu awọn to wa nibi agbekalẹ eto iṣuna naa ni Igbakeji gomina, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele, Tunji Ẹgbẹtokun, Salamat Badru, Titi Oseni-Gomez ati bẹẹ bẹẹ lọ.