Dapọ Abiọdun gbe iṣuna ọdun 2021 kalẹ fawọn aṣofin

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti gbe aba eto iṣuna ipinlẹ yii fọdun to n bọ lọ siwaju ile igbimọ aṣofin Ogun.
Ọjọruu, ọjọ keji oṣu kejila yii lo gbe bọjẹẹti onibiliọnu ọ̀ọ́dúnrún le mọkandinlogoji (339bn) naa lọ sọdọ awọn igbimọ naa lati buwọ lu.
Akọle ti wọn fun bọjẹẹti naa ni ‘Budget of Recovery and Sustainability’, eyi ti itumọ rẹ jẹ iṣuna ti yoo da ikolo pada ti yoo si gbe awọn eto to wa nilẹ ro.
Ọgọrun-un kan ati mẹtadinlọgọrin (177bn) nijọba ya sọtọ fun awọn iṣẹ olowo nla ti yoo da wọle. Biliọnu ọgọrun-un kan le mejilelọgọta (162bn) ni wọn yoo si naa lori awọn owo iṣẹ tawọn eeyan ba ṣe funjọba.
Biliọnu mọkanlelọgọta(61bn)  ni yoo ba eto amayedẹrun lọ, awọn eto bii ilera, ile gbigbe, aato ilu ati ayika pẹlu ọrọ awọn obinrin yoo si jẹ biliọnu mẹtadinlọgọrun-un (93bn).
Gẹgẹ bi Gomina Abiọdun ṣe wi, biliọnu mejidinlọgọta (58bn) nijọba yoo na lori eto ẹkọ lọdun to n bọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: