Dapọ Abiọdun ti ileewe pa l’Ogun, o fofin de ọkada fungba diẹ na

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti paṣẹ pe ki gbogbo ileewe jake-jado ipinlẹ Ogun ṣi wa ni titi pa titi di ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa yii, latari bi awọn to n fẹhonu han nitori SARS ṣe ti sọ kinni naa di wahala rẹpẹtẹ.

Yatọ sawọn ileewe, gomina tun paṣẹ pe awọn ọlọkada ko gbọdọ ṣiṣẹ nipinlẹ Ogun fun wakati mẹrinlelogun, paapaa Ọjọruu, ọsẹ yii, ti i ṣe Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa yii.

Ọfiisi Gomina Abiọdun to wa l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta, lo ti sọ eyi di mimọ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu kẹwaa yii.

Ọmọọba Abiọdun sọ pe ko sohun to jẹ ki isede kan awọn ọlọkada ju bo ṣe jẹ pe alupupu wọn lọpọ awọn janduku n gun lọọ da ilu ru kaakiri. Koda, o ni aṣọbode kan padanu ẹmi ẹ lọjọ Iṣẹgun yii, ọkada naa ni wọn si gun lọọ pa a ni ọkan ninu awọn ilu ẹnu ibode nipinlẹ Ogun.

 

Gomina ṣalaye pe pẹlu gbogbo bi ijọba ṣe fi ohun tutu ba awọn ọdọ to n ṣewọde naa sọrọ to, o ṣe ni laaanu pe niṣe ni wọn sọ iwọde naa di a n di oju ọna pa, to bẹẹ tawọn eeyan ko ri ibi iṣẹ wọn de, ti ọpọ eeyan si ti sọ ẹmi wọn nu lojiji.

O tẹsiwaju pe ijọba yoo ko awọn agbofinro jade lati fopin si bawọn oluwọde naa ṣe n gbegi di ọna, wọn ko si ni i gba fawọn to n ba dukia ijọba jẹ mọ, nitori ọpọ nnkan ijọba lawọn kan ti sọna si, ti wọn ba ọpọlọpọ mọto jẹ, ti wọn tun ṣe awọn agbofinro leṣe.

Gomina Abiọdun waa rọ awọn obi, alagbatọ, awọn ọba ati baalẹ kaakiri, pe ki wọn ba awọn eeyan wọn sọrọ, ki kaluku fa ọmọ rẹ leti, ọmọkọmọ to ba kọ eti ọgbọin si ikilọ ijọba yii yoo da ara rẹ lẹbi ni gomina wi.

O pari alaye naa pe ni gbogbo wakati mẹrinlelogun nijọba yoo maa ṣagbeyẹwọ ohun to n ṣẹlẹ ati ipa to n ni lara ilu, ẹsẹkẹsẹ naa lawọn yoo si maa kede ayipada to ba yẹ fun iṣẹlẹ kọọkan.

Leave a Reply