Dessers darapọ mọ Genk ilẹ Belgium

Oluyinka Soyemi

Atamatase ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles tuntun, Cyriel Dessers, ti darapọ mọ Kilọọbu Genk ilẹ Belgium fun ọdun mẹrin.

Heracles Almero ilẹ Netherlands lọmọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn naa ti kuro lẹyin ọdun kan, bọọlu mejidinlogun lo si gba wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlọgbọn nibẹ.

Genk ni kilọọbu kẹfa ti Dessers yoo ti gba bọọlu, bẹẹ lo jẹ pe laarin orilẹ-ede Belgium ati Netherlands lo ti n lọ lati kilọọbu kan si ekeji.

Ọmọ ilẹ Belgium ni baba agbabọọlu yii, ṣugbọn ọmọ Naijria ni iya rẹ, eyi lo ṣe pinnu lati maa kopa fun Super Eagles ilẹ wa.

Leave a Reply