Diẹ lo ku kawọn Fulani gun Kereku pa l’Ayetẹ, nigba tibọn wọn ko ran an

Faith Adebọla

Bo tilẹ jẹ pe ọsibitu Ojumu, niluu Igangan, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, ipinlẹ Ọyọ, ni baba agbẹ ẹni ọdun marundinlaaadọta kan ti wọn porukọ ẹ ni Kereku Yanmi wa lasiko yii, ṣibẹ, orin ọpẹ ni baba naa yoo maa kọ pẹlu bi iku ojiji tawọn Fulani darandaran kan ti wọn ka a mọ oko rẹ fẹẹ fi pa a, ṣugbọn ti wọn lọta ibọn ti wọn yin si i ko wọle, ko si tu irun kan lara baba naa.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, la gbọ pe iṣẹlẹ yii waye, ọwọ aṣaalẹ ni wọn ni baba naa n dari bọ lati oko rẹ to wa ni Ọyankalu, nitosi abule Lukosi, to jẹ ọkan ninu awọn arọko ilu Ayetẹ.

Wọn ni niṣe lawọn apamọlẹkun Fulani darandaran naa ṣadeede yọ si baba yii latẹyin, wọn si paṣẹ fun un ko duro, ṣugbọn baba naa ko duro, eyi lo mu ki wọn yinbọn fun un.

O jọ pe baba naa ti dọgbọn sọrọ ara rẹ, latari bi wọn ṣe ni ibọn ti wọn yin si i ko ran an, eyi lo mu kawọn Fulani sun mọ ọn, ti wọn si fọbẹ ṣa a lẹyin ọrun, bo tilẹ jẹ pe baba yii raaye sa mọ wọn lọwọ.

Alakooso ẹgbẹ idagbasoke ilu Igangan (Igangan Development Advocates), Ọgbẹni Ọladiran Ọladokun, sọ f’ALAROYE AKEDE AGBAYE pe awọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa tẹṣan Igangan ati Ayetẹ leti. O lawọn Fulani apaayan kan ṣi wa ninu awọn ọna oko ilẹ Ibarapa ti wọn fori pamọ lati maa ṣe awọn agbẹ ni ṣuta, o si jọ pe awọn agbofinro ko ti i ṣetan lati gbe igbesẹ lodi si wọn.

O lawọn tun maa lọọ kegbajare si gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, lẹẹkan si i.

A ṣapa lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọpa sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn ko gbe aago rẹ titi ta a fi ko iroyin yii jọ.

Leave a Reply