Faith Adebọla, Eko
Oṣu mẹẹẹdogun gbako nijọba ipinlẹ Eko lawọn maa fi ti awọn ọna kan pa lagbegbe Ikẹja, lati le pese aaye fun iṣẹ ọna reluwee tuntun ti wọn n gbero lati la sagbegbe ọhun.
Kọmiṣanna feto irinna nipinlẹ Eko, Ọmọwee Frederick Ọladẹinde, lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, ninu atẹjade kan.
O ni eto ti pari lati bẹrẹ iṣẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lori ọna reluwee to maa gba aarin ilu kọja lawọn agbegbe kan, Red Line project ni wọn pe iṣẹ ode ọhun, labẹ eto tijọba ipinlẹ Eko n ṣe lati mu ki eto irinna reluwee dele-doko nipinlẹ ọhun.
Ọladẹinde ni lati ọjọ Sannde yii lawọn ti maa bẹrẹ si i dari awọn ọkọ to n jade lati ọja igbalode Computer Village ati ọna Simbiat Abiọla, n’Ikẹja, ti wọn si fẹẹ kọja si ọna marose Eko si Abẹokuta. Opopona Akinrẹmi ni wọn maa tọ jade si Oponona Oṣifila, ti wọn yoo fi gba oju irin reluwee sọda sibi ti wọn n lọ, dipo ọna ti wọn ti n gba tẹlẹ.
Bakan naa lo lawọn maa dari awọn ọkọ to fẹẹ ya s’Ikẹja latori titi Eko s’Abẹokuta gba Opopona Balogun, ti wọn aa fi jade si Opopona Oduyẹmi, ibẹ ni wọn yoo gba bọ si ọna Ọbafẹmi Awolọwọ, n’Ikẹja, ti wọn yoo si le tẹsiwaju sibikibi ti wọn ba fẹẹ lọ.
Oduyẹmi fọkan awọn onimọto ati araalu balẹ, o ni pẹlẹkutu lawọn maa maa dari ọkọ, tawọn si maa kọ awọn agbofinro sọna, lati dena akọlukọgba tabi ijamba titi tiṣẹ ọna reluwee naa maa fi pari.
Kọmiṣanna lawọn ti ṣeto lati ri awọn sainbọọdu sawọn ibi to yẹ, ko le maa tọ awọn ọlọkọ sọna, ki wọn si le mọ ibi ti wọn maa gba lai si wahala, nitori iru sainbọọdu gadagba kan bẹẹ maa wa labẹ biriiji Ikẹja, ti yoo juwe bawọn ọnimọto ṣe maa rin ti wọn yoo fi debi ti wọn n lọ nirọrun fun wọn.