Dino Melaye ṣe fidio tuntun fun Tinubu pẹlu Ọshiomohle

Aderounmu Kazeem

Ibo Edo ti waye, bẹẹ lo ti lọ o, ṣugbọn o jọ pe awọn oloṣelu kan wa ti ọrọ ọhun ṣe leemọ gidi, bẹe lawọn gan-an mọ pe, nnkan nla lo ṣe wọn.

Ni Nigeria loni-in, ko si bi awọn eeyan ṣe fẹẹ sọrọ ibo Edo, ti wọn ko ni i darukọ Obaseki, Ize Iyamu, bẹẹ ni orukọ alaga ẹgbẹ APC tẹlẹ yoo tẹle e, iyẹn  Adams Oshomhole, ti wọn yoo tun fi ti Aṣiwaju Bọla Tinubu kun un.

Ọkunrin kan wa, Dino Melaye lo n jẹ, ṣẹyin naa ranti Sẹnetọ ọmọ ipinlẹ Kogi to fẹran awada daadaa lori ẹrọ ayarabiiaṣa, intanẹẹti, oun lo gba ibẹ lọ o, to si ṣe fidio orin tuntun jade. Ninu ẹ, bo ṣe n fi Oshimhole ṣe yẹyẹ, bẹẹ lo n darukọ Tinubu naa. Ohun kan to si n sọ ni pe, Oshiomhole ki i ṣe “Oshio baba” mọ o, “Oshio pikin” ni. Eyi tumọ si pe Oshiomhole ki i ṣe agba ọjẹ kankan mọ ta a ba n sọ nipa oloṣelu to lẹnu.

O ni agbara ọkunrin naa ti tan patapata nidii oṣelu, bo ti ṣe kuna gẹgẹ bi alaga APC nijọsi, to tun waa fidi janlẹ nipinlẹ ẹ naa bayii.

Bẹẹ gẹgẹ lo tun sọ ti Tinubu naa, to ni gbogbo gra-gra awọn agba oloṣelu yii, Ọnburẹda ẹgbẹ PDP lo rile gba isansa awọn eeyan si, nitori ninu ojo gan-an lọnburẹda ti maa n wulo daadaa.

Ni ti Bọla Tinubu yii,  Dino ni ọkunrin oloṣelu yii iba ti jokoo jẹẹ s’Ekoo, ko ma loun fẹẹ ba awọn eeyan Edo sọrọ kankan nigba ti ibo ku si dẹdẹ, nitori ibinu wi pe Edo ki i ṣe Eko gan-an pẹlu ohun to fa sababi ibo olooyi ti won fi le ẹgbẹ oṣelu APC danu l’Edo.

Leave a Reply