Dokita Amẹrika ti ni ki wọn ma sọ pe ko soogun fun korona mọ, oogun ẹ wa o jare

Obinrin oniṣegun oyinbo kan ni orilẹ-ede Amerika, Dokita Stella Emmanuel, ti sọ pe oogun wa fun ajakalẹ arun to n da gbogbo aye laamu ti wọn n pe ni koronafairọọsi. O ni o dun oun, o si n ba oun ninu jẹ pe awọn ti wọn n ta oogun oyinbo ti wọn si n fẹẹ pa owo n sọ fawọn eeyan pe ko si oogun fun arun yii, pe awọn ṣii n w aoogun ti yoo gbọ arun naa ni. O ni ọrọ naa ko daa o.

Dokita Emmanuel ni, ni toun, oun ti fi oogun kan ti wọn n pe ni hydroxychloroquine, oogun ti awa n pe ni kolorokuin nibi, wo bii aadọtalelọọdunrun (350) eeyan san lọdọ oun. O ni ojoojumọ ni wọn n waa ba oun lọsibitu, ojoojumọ loun si n wo wọn san pẹlu kolorokuin.

Ṣugbon ọpọ awon oniṣegun ni Amẹrika, ati ni awọn orilẹ-ede mi-in ni wọn ti sọ pe ki ẹnikẹni ma da Dokita Emmanuel to jẹ ọmọ Afrika lohun o, nitori bo ba jẹ kolorokuin lasan kapa kinni naa ni, oku rẹpẹtẹ bẹẹ ko ni i sun ni Amẹrika, Brazil, Mexico ati awọn orilẹ-ede Yuroopu (Europe) nitori gbogbo wọn yii lo mọ nipa kolorokuin daadaa ju dokita naa lọ.

Ijọba Naijiria paapaa ti sọrọ, wọn ni awọn ko i ti dan kolorokuin ti obinrin yii n sọ wo lati fi wo arun koronafairọọsi o, kẹnikẹni ma si ṣe tẹ le awọn ohun to sọ pe ko sẹni to niloo ibomu mọ, nigba ti oogun ti yoo pa arun naa ba de, gbogbo aye ni yoo mọ. Ṣugbọn ni bayii, ki kaluku maa ṣọra wọn, ki wọn mọ pe arun to n paayan ni koronafairọọsi, aye ko si ti i ri oogun gidi fun un.

Leave a Reply