Jamiu Abayomi
Awọn ọtẹlẹmuyẹ (DSS), ti wọ gomina banki ile-ifowopamọ apapọ ilẹ wa (CBN), ti wọn ti da duro tẹlẹ, Godwin Emefiele, lọ sile-ẹjọ bayii.
Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun yii, ni ile-ẹjọ to ga ju lọ l’Abuja paṣẹ pe ki wọn wọ ọkunrin naa lọ sile-ẹjọ tabi ki wọn tu u silẹ. Adajọ naa ni dide ti wọn de Emefiele mọlẹ lai ni pato ẹsun kan ti wọn ka si i lẹsẹ ko daa, bẹẹ ni ko ba ofin mu. O ni ti wọn ko ba ti le gbe e lo si kootu, ki wọn tu u silẹ ko maa lọ ile ẹ layọ ati alaafia.
Agbẹnusọ awọn DSS, Peter Afunanya, sọ pe loootọ ni ile-ẹjọ paṣẹ pe ki awọn gbe ọga banki apapọ ilẹ wa tẹlẹ yii lọ sile-ẹjọ, tawọn si ti ṣe bẹẹ, ṣugbọn ọkunrin naa ko sọ asiko ati orukọ ile-ẹjọ ti wọn gbe Emefiele lọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Aarẹ Bọla Tinubu da Emefiele duro gẹgẹ bii gomina ile ifowopamọ apapọ (CBN), to si ni ki igbakeji rẹ, Folashodun Adebisi Shonubi maa baṣe lọ.