Dubai lawọn eleyii ti waa ṣe ‘Yahoo’ l’Ekoo ti EFCC fi mu gbogbo wọn

Faith Adebọla, Eko

 

Orileede United Arab Emirates, ti Dubai jẹ olu-ilu rẹ, ni wọn lawọn mẹta yii n gbe, Samuel Oluwaṣẹgun Ọlayinka, Afeez Fajumọbi ati Ọlamilekan Ọlaofẹ, ki wọn too wa si Naijiria loṣu kejila to kọja, ṣugbọn akolo ajọ to n gbogun ti iwa jibiti lilu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, ni wọn wa bayii, Eko ni wọn ti mu wọn fun ẹsun jibiti ori atẹ ayelujara ti wọn n pe ni ‘Yahoo’.

Awon-meta-ti-won-n-wa-lati-Dubai-waa-ṣe-jibiti-Yahoo.

Ki i ṣawọn mẹta yii nikan o, ọwọ tun ba awọn mẹrinla mi-in to jẹ Naijiria, nipinlẹ Eko, lawọn n gbe ni tiwọn, ṣugbọn iwa apamọlẹkun-jaye, jibiti ‘Yahoo’ yii lawọn naa mu bii iṣẹ.

Orukọ awọn mẹrinla ọhun ni: Oluwatobi Amao, Joshua Amao, Ọlatunde Adeyẹmọ, Solomon Emelike, Lawrence Nwodu ati Ọlamilekan Philip

Awọn to ku ni Ibrahim Ọgbẹnusi, Sadiq Adewale, Collins Kelechi Ndubuka, John Okafor Eze, Lateef Adewale, Hassan Mohammed, Hussaini Adebayọ ati Babatunde Lawal.

Alukoro EFCC, Ọgbẹni Wilson Uwajuren, to sọrọ yii f’ALAROYE sọ pe Ojule kọkanlelogoji, Opopona Muritala Eletu Osapa London, lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, lọwọ ti ba gbogbo wọn l’Ọjọbọ, Wẹsidee yii, lẹyin tawọn kan ti ṣofofo fun EFCC pe irin awọn afurasi naa gba ifura gidi.

Ẹrọ kọmputa alaagbeletan mọkanla, awọn eroja abanaṣiṣẹ ti wọn fi n so mọ intanẹẹti, oogun abẹnu gọngọ, awọn ẹrọ alagbeekan olowo iyebiye wa lara awọn irinṣẹ ti wọn ba lakata awọn afurasi ọdaran wọnyi.

Ṣa, gbogbọ wọn ti n ran awọn agbofinro lọwọ lẹnu iwadii wọn, gẹgẹ bi Uwajuren ṣe wi. O ni gbogbo wọn maa too ba ara wọn nile-ẹjọ laipẹ tiṣẹ iwadii ba ti pari, ki wọn le ṣalaye ara wọn fadajọ.

Leave a Reply