Ọjọ mẹfa ni mo fi sun inu igbó lahaamọ awọn Fulani ajinigbe- Alaga kansu

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Alaga ijọba ibilẹ onidagbasoke Iganna, lagbegbe Ibarapa, nipínlẹ Ọyọ, Ọnarebu Ọlayiwọla Adeleke, ti ṣalaye ohun ti awọn Fúlàní foju ẹ ri laarin ọjọ mẹfa to lo lakata wọn.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bíi aago mẹrin aabọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣù kẹwàá, ọdún 2020, lawọn gende ọkunrin agbébọn mẹjọ kan da alaga kansu náà lọnà lasiko to n lọ fún ipade pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, tí wọn sì ji i gbe.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Igangan, ti i ṣe olu ilu ijọba ibilẹ Onidagbasoke Iganna l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, Ọnarebu Adeleke ṣalaye pe “Ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹwàá, ọdún tó kọjá, la fẹẹ ṣepade yẹn, ṣugbọn mo pinnu lati lọọ sun Ibadan lọjọ Sannde ti ìpàdé yẹn ku ọla, ki n ma baa pẹẹ débẹ̀.

“Bá a ṣe de Gboga, lọna ilu Ado-Awaye la kan deede bẹrẹ si i gburoo ibọn tàkòtàkò. Nígbà ti awakọ mi fi máa tọ́ọ̀nù pada, awọn eeyan yẹn ti kan wa lara.

“Wọn bẹrẹ si í gba emi atawakọ mi loju, gba wa létí. Bẹẹ ni wọn n yinbọn soke lati dẹru ba awọn eeyan to ṣee ṣe kí wọn waa gba wa silẹ.

“Lẹyin naa ni wọn taari wa lọ́pọnpọ̀n-ọ́n lọ sinu Igbo.

“Ori àpáta kan la sun loru ọjọ Sannde yẹn. Bi ilẹ ọjọ keji ṣe mọ ni wọn tun mu wa tẹsiwaju ninu Irinajo ninu aginjù igbo yẹn. Inu aginju yìí la sì sun lọjọ Mọndé yẹn.

“O han daju pe wọn ti máa n lọ inu igbo yẹn tipẹ fun ijinigbe nitori wọn ti mọ-ọn-mọ ṣe ibi ti won n kó wa pamọ sí yẹn gẹgẹ bíi igbekun ti wọn n ko àwọn èèyàn tí wọn bá ti ji gbe sí.

“Ni nnkan bii aago meje alẹ ni wọn fún mi ni foonu mi pe ki n fi pe awọn ẹbi mi.

“Ṣaaju asiko yẹn, wọn ti gba gbogbo nnkan to wa lọwọ wa silẹ. Wọn gba foonu mi ati baagi ti mo ko àwọn dọ́kúmẹ́ǹtì kan sí pẹlu owo tí mo fẹẹ fi sanwo ileewe ọmọ mi kan.

“Mílíọ̀nù lọna igba Naira (#200m) ni wọn kọkọ sọ pe awọn máa gba lọwọ awọn ẹbi mi ki wọn too bẹ wọn lati gba mílíọ̀nù marun-un naira ataabọ ti wọn padà san fún wọn ki wọn tóo fi mi silẹ yẹn.”

Awọn ara Ibarapa ti wọn ti ko ṣọwọ awọn ajinigbe ri naa ba awọn oniroyin sọrọ. Iriri tiwọn naa kò sí fi bẹẹ yatọ si alaye ti alaga kansu to ti sọrọ ṣaaju ṣe.

Wọn waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ ìṣàkóso Gomina Ṣeyi Makinde, lati le gbogbo awọn Fúlàní ipinle yii danu, nitori aburu ti wọn n ṣe pọ ju daadaa ti wọn n ṣe fún àwọn ọmọ Yorùbá lọ

Leave a Reply