Lasiko tawọn adigunjale meji fẹẹ bọ Ogun nitori ibọn wọn lawọn ọlọpaa ka wọn mọ l’Ejigbo

Faith Adebọla, Eko

 

Ibi tawọn afurasi adigunjale meji kan, Ọpẹyẹmi Adegboyega, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ati Dernard Ahor, ẹni ọdun marundinlogoji, loṣoo si pẹlu ibọn meji ọwọ wọn ti wọn ko kalẹ si ojubọ Ogun, ti wọn n reti Abọrẹ Ogun to maa waa wure fun ibọn wọn, ibẹ lawọn ọlọpaa ka awọn mejeeji mọ, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, to fi ọrọ yii to ALAROYE leti ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sọ pe niṣẹ lawọn afurasi ọdaran ọhun lọọ ba Ọgbẹni Lawrence Adeniji, tawọn eeyan mọ si Abọrẹ OPC, wọn ni awọn fẹẹ bọ Ogun, awọn fẹ ko ṣadura kawọn ma ṣe ri ija Ogun, ko si ṣadura fun irinṣẹ awọn naa.

Abọrẹ ni iyẹn o le, o ka awọn nnkan eelo ti wọn maa mu wa fun wọn, titi kan adiyẹ ati ọti ṣinaapu, o si ni ki wọn gbe irinṣẹ ti wọn fẹẹ gbadura le lori naa wa, boya Abọrẹ yii ro pe mọto tabi ọkada ni.

Afi bo ṣe di ọjọ ti wọn fadehun si, Ọpẹyẹmi ati Dernard ko awọn nnkan etutu wa loootọ, ṣugbọn ibọn ilewọ pompo meji ni wọn fa yọ ninu baagi wọn, wọn ni irinṣẹ tawọn fẹẹ tori ẹ bọ’gun niyẹn, l’Abọrẹ ba ni ki wọn ko wọn kalẹ si ojubọ Ogun, ki wọn jokoo ti i, koun sare mura ati ṣetutu ọhun fun wọn.

Adejọbi ni bi Lawrence ṣe bọ si kọrọ kan lo tẹ ileeṣẹ ọlọpaa Ejigbo laago, pe ki wọn waa wo ohun toju oun ri. Oju ẹsẹ si lawọn ọlọpaa ti kan wọn lara, ori iloṣoo tawọn afurasi naa bẹrẹ mọlẹ si ni wọn ba wọn, bi wọn si ṣe bi wọn leere ibi ti wọn ti ri ibọn ati iṣẹ ti wọn fẹẹ fi ibọn ṣe, niṣe lọrọ pesi jẹ, ni wọn ba n tẹwọ pe ki wọn ṣaanu awọn.

Nigba ti wọn tu ẹru wọn, wọn ba katiriiji mẹjọ awọn ọta ibọn ti wọn o ti i yin, ọbẹ aṣooro kan, ṣeeni ọrun ọwọ kan, foonu olowo nla (iPhone) meji, foonu Nokia kan, foonu Tecno kan, atawọn oogun abẹnu gọngọ loriṣiiriṣii.

Ṣa, awọn ọlọpaa ti mu wọn, Hakeem Odumosu, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, si ti paṣẹ pe ki wọn fi wọn ṣọwọ sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, lati tubọ wadii iṣẹlẹ yii.

Adejọbi lawọn afurasi naa maa balẹ si kootu tiwadii ba ti pari

Leave a Reply