Ẹẹmẹta lọkọ mi fun mi lowo lati ṣẹyun, latigba naa ni ko ti nifẹẹ mi mọ – Ọmọtayọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

”Mo fẹẹ kọ ọkọ mi silẹ nitori ko nifẹẹ mi. Oyun mẹta lo ti ṣẹ fun mi. ti mo ba ti loyun lo maa fun mi lowo pe ki n lọọ ṣẹ ẹ danu, aa loun ko nilo ọmọ. Nigba ti oyun ṣiṣẹ su mi ni mo bimọ kan, latigba naa ni ko si ti nifẹẹ mi mọ.”

Iyawo ile kan, Ọmọtayọ Babatunde, lo ṣe bayii sọrọ nigba to n gbiyanju lati kọ ọkọ ẹ, Lateef Babatunde, silẹ ni kootu ibilẹ Ile-Tuntun, to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan.

O tẹsiwaju pe, “Bi ọmọ ṣe pe oṣu mẹta lo ti fi emi atọmọ silẹ, to sa kuro nile, odidi ọdun meji lo si lo lẹyin odi ko too pada wale.”

“Nigba to ya lo bẹrẹ si i fẹsun kan mi pe mo n pẹẹ wọle lati ibi iṣẹ. Mo si dahun pe iwọ lo fa a, ṣebi nigba too fi emi atọmọ silẹ ni mo bẹrẹ si i se ounjẹ ta.

“O ti lọọ ba awọn ẹbi mi pe oun ko fẹ mi mọ. iyẹn lo jẹ ki n ko jade nile ẹ bayii ki n too pinnu lati kuku kọ ọ silẹ nile-ẹjọ yii.’’

Olujẹjọ, Lateef Babatunde, sọ pe oun naa fara mọ kile-ẹjọ tu igbeyawo awọn ka nitori pe alagbere obinrin niyawo oun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Emi o mọ nipa awọn oyun to sọ pe oun ni, oun lo n wa gbogbo ọna lati bimọ. Nigba to loyun, mo fun un lowo pe ko lọọ ṣẹ ẹ, iyẹn nikan si loyun ti mo ni ko ṣẹ.”

Ọkunrin awakọ to n gbe adugbo Boluwaji, n’Ibadan yii, fi kun un pe “Emi kọ ni mo le e jade nile mi, oun lo jade funra rẹ nitori ko le maa raaye huwa agbere. Mi o mọ nipa ọmọ to bi yẹn paapaa. Nigba tọkunrin mi-in fun un loyun yẹn la fitiju kuro nile ta a n gbe tẹlẹ. Ẹẹmeji ni mo ti fẹjọ ẹ sun mama ẹ nipa iwa agbere to n hu, ṣugbọn ti ko yipada bi wọn ṣe ba a sọrọ to.

“Lọjọ kan, ara mi ko ya, mo ni ko lọọ ba mi ra oogun iba wa. Nigba ti ko tete de ni mo wa a lọ. Mo ba ri i pẹlu ọkunrin kan ti wọn jọ n sọrọ ninu ọkọ Toyota Camry.  Mo lọọ ba a lẹgbẹẹ ẹni ti wọn jọ n sọrọ yẹn, mo ni oogun ti mo ran ẹ da, kaka ko tiẹ fi itiju tabi ibẹru dide lẹgbẹẹ ẹni yẹn, o kan rọra fi oogun yẹn le mi lọwọ ni, wọn si tun n ba ọrọ wọn lọ.

“Mo waa foonu aburo ẹ pe tete maa bọ, wọn ti n lu aunti rẹ. Nigba ti iyẹn sare de, mo naka sọọọkan, mo ni aunti ẹ niyẹn, oun naa si lọọ wo o nibi to ti n ba ọkọ ọkunrin yẹn sọrọ ninu mọto. Nitori ki n le lẹlẹrii ni mo ṣe dọgbọn pe aburo rẹ waa wo o lọjọ yẹn.

“Njẹ ẹ jẹ mọ pe aago meji oru niyawo mi too wọle lọjọ yẹn. Nigba to ji laaarọ ọjọ keji, niṣe lo jokoo kalẹ  lai mu iṣẹ kankan ṣe, mo ni ṣe o ko tiẹ ni i gbalẹ ile ati ayika ni, o kan fi mi gun lágídi ni. Ibi iṣẹ ni mo wa lọjọ naa ti awọn araadugbo ti pe mi pe iyawo mi ti mu mọto wale, o ti waa ko awọn ẹru ẹ lọ.

Ile-ẹjọ ti tu igbeyawo ọlọdun meje to seso ọmọ kan ọhun ka. Olupẹjọ ni wọn yọnda ọmọ fun, wọn si paṣẹ fun olujẹjọ lati maa san ẹgbẹrun marun-un Naira fun iyawo rẹ atijọ yii lati maa fi wa ounjẹ fọmọ to bi fun un naa.

Leave a Reply