Ẹgbẹrun kan naira la ta ori awọn ọlọpaa mejeeji ta a gbe lọjọsi, aafaa kan n’Ilọrin lo fẹẹ fi wọn ṣoogun owo – Awọn afurasi ọdaran

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ọsẹ mẹrin ti awọn ọmọ iṣọta ti dana sun ọlọpaa meji laduugbo Iwo Road, n’Ibadan, ti wọn si pin ẹran ara wọn jẹ bii ẹni jẹ suya laarin ara wọn, ọwọ awọn agbofinfro ti tun tẹ awọn ti wọn gbe koronfo agbari awọn ọlọpaa naa.

Ọmọọdun mẹtadinlogun kan, Adewale Abiọdun ati Aliu Mubarak ti oun jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun ni wọn ṣiṣẹ ibi naa. Atawọn ati onịṣegun ibilẹ ti wọn ta a fun, Ọladipupọ Ifakorede, lawọn agbofinro jọ ṣa lọkọọkan nibi ti kaluku wọn fori pamọ si.

Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii, lawọn ọmọ iṣọta dana sun awọn sajẹnti ọlọpaa meji kan, Ajibọla Adegoke ati Rotimi Ọladele, lasiko ti wọn n lọ sẹnu iṣẹ, wọn ni wọn fi mọto gba ọlọkada kan, iyẹn si ṣe bẹẹ jade laye.

Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ẹni to ṣafihan awọn afurasi ọdaran naa fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, fidi ẹ mulẹ pe lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla, ọdun 2020 yii, lọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa ba awọn olubi eeyan naa.

Ninu ifọrọwerọ ti awọn oniroyin ṣe pẹlu ẹ, eyi to n jẹ Abiọdun ninu awọn afurasi ọdaran yii sọ pe ọtọ nibi ti awọn n lọ lọjọ naa, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, ti awọn fi ri i ti wọn n kun ẹran eeyan bii ẹni kun adiẹ, ti Murarak si sọ pe ki awọn lọọ gbe ori awọn oku eeyan naa.

O ṣalaye pe “Nigba ta a de Iwo Road, a ri i pe gbogbo ọna ti di pa. Wọn dana soju titi. Awa naa sun mọ ibẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ, a waa ri i pe awọn eeyan meji kan ni wọn dana sun, wọn lọlọpaa lawọn mejeeji.

“A ri i ti wọn n fi igi lu oku awọn ọlọpaa yẹn, bẹẹ ni wọn tun fa ẹya ara wọn yọ lọkọọkan, ti kaluku si n mu eyi to ba fẹ nibẹ.

“Mubarak sọ pe oun naa fẹẹ lọọ mu diẹ ninu awọn ẹya ara yẹn. mo ni ki lo fẹẹ fi wọn ṣe, o loun mọ oniṣegun kan ti oun maa ta wọn fun. Bo ṣe gbe ori awọn ọlọpaa mejeeji niyẹn.

“Oniṣegun kan (Ifakorede) ta a jọ n gbe adugbo la lọọ fun. Ẹgbẹrun kan Naira (N1,000) lo ra a, o ni ki i ṣoun loun fẹẹ lo o,  aafaa kan n’Ilọrin loun fẹẹ lọọ ko wọn fun, oun lo mọ bo ṣe n lo wọn fun oogun owo.

“Apo meji aabọ (N500) ni wọn fun wa ninu owo yẹn. lẹsẹkẹsẹ lemi ati Mubarak ti lọọ fii jẹun. Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ yẹn ni mo pada ri oniṣegun yẹn to fun mi ni apo meji aabọ yooku ti emi ati Mubarak si jọ pin in ni túú túú fifitì (N250)”.

Alaye ti Mubarak naa ṣe ko yatọ si ti ọrẹ ẹ, o ni oun loun dabaa pe ki awọn ko ori awọn ọlọpaa ti awọn eeyan dana sun laduugbo Iwo Road ọhun nitori oun mọ pe owo ni kinni naa yoo yọ fawọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mo wa ọra poli baagi kan, mo ko ori mejeeji si. A si gbe wọn lọ sile. Nigba to di aago marun-un irọlẹ la lọọ gbe e fun Ifakorede.

“Oju ọna la ti pade ẹ, a waa sọ fun un pe a ni eegun agbari awọn ọlọpaa meji kan ta a fẹẹ ta fun wọn, o waa ni a ko gbọdọ sọ fẹnikankan o. O si fun wa ni apo meji aabọ ninu ẹgbẹrun kan Naira to sọ pe oun maa ra ori mejeeji. Lẹyin naa lo fun Abiọdun niyooku, ta a si jọ pin in dọgbandọgba.”

Ifakorede, oniṣegun ibilẹ ti wọn ta awọn eegun agbari ọlọpaa mejeeji fun naa jẹwọ pe oun ni wọn taja okunkun ọhun fun loootọ, ati pe ẹgbẹrun mẹta Naira ni wọn da le awọn agbari naa ki oun too sọ oju abẹ nikoo pe oun ko le san ju ẹgbẹrun kan Naira lọ.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lati ri awọn yooku ti wọn lọwọ ninu ọran naa mu gẹgẹ bi ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu ṣe fidi ẹ mulẹ.

Leave a Reply