Ẹ ba mi wa ṣọja to lu ọmọ mi pa jade o, Baba Yinka figbe bọnu n’Ileṣa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Baba ẹni ọdun mọkandinlọgọrin kan, Pa David Adekunle, ti kegbajare si awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun orileede wa lati ṣewadii iku to pa ọmọkunrin kan ṣoṣo to bi, Yinka, ẹni ti wọn ni ọkunrin ṣọja kan fiya jẹ doju iku ni baraaki wọn to wa ni Ibodi, niluu Ileṣa.
Gẹgẹ bi baba naa ṣe sọ, ṣe ni awọn ṣọja ọhun tan Yinka lọ si baraaki wọn lẹyin ti wọn jọ ni gbolohun asọ nile-igbafẹ kan pẹlu awọn ọrẹ rẹ meji l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.
O ṣalaye pe, “Yinka atawọn ọrẹ rẹ meji ni wọn jọ lọ sile igbafẹ kan lagbegbe Fadahunsi, niluu Ileṣa, wọn si ba awọn ọkunrin mẹta kan nibẹ. Ariyanjiyan kan bẹ silẹ laarin wọn, bi n ko tiẹ mọ ohun to ṣẹlẹ, ṣugbọn Yinka atawọn ọrẹ rẹ ko mọ pe ṣọja ni wọn.
“Mo gbọ pe ọkan lara awọn ṣọja yẹn dọgbọn bọ sita, o si pada pẹlu mọto ileeṣẹ ologun to kun fun awọn sọja. Bayii ni Yinka ati ọkan lara awọn ọrẹ rẹ sa lọ, ti awọn ṣọja si gbe ẹni kẹta wọn lọ si baraaki wọn to wa n’Ibodi, wọn si tun gbe mọto Lexus 350 ti ọmọ mi gbe lọ sibẹ lọ.
“Lọjọ keji, mo gbọ pe Yinka gba ipe kan latọdọ awọn ṣọja pe ko waa gbe mọto rẹ, ko si waa beeli ọrẹ rẹ ti wọn mu. Alọ Yinka la ri, a ko ri abọ rẹ.

“Lọjọ Satide, ọkan lara awọn ọrẹ rẹ pe mi pe ki n lọọ wo o n’Ibodi, nitori o ni ede aiyede pẹlu awọn ṣọja. Lẹnu ọna baraaki ni wọn ti sọ fun mi pe wọn ti gbe e lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ayesọ. Bi mo tun ṣe de Ayesọ ni wọn sọ fun mi pe ki n lọọ wo o ni Wesley Guild Hospital, Ileṣa.
“Nigba ti mo debẹ, mo sọ fun wọn pe ṣọja lo gbe ẹni ti mo n wa wa si ọsibitu, wọn si sọ fun mi pe ki n lọọ wo o nile igbokuu-pamọ-si, aya mi ja nigba ti mo ri oku ọmọ mi. Ẹni ti mo ba nibẹ jẹ ko ye mi pe ṣọja kan lo kọkọ gbe oku rẹ wa, ṣugbọn awọn ko gba a lọwọ ẹ, awọn si sọ pe ko lọ̣ọ mu akọsilẹ ọlọpaa wa.
“O ni lẹyin igba naa ni ọkunrin kan to n jẹ Martins lati agọ ọlọpaa Ayesọ yan awọn ọlọpaa meji tẹle oku Yinka, ti wọn si gbe e wa si ọsibitu yẹn. Apa (marks) oriṣiiriṣii lo wa lara ọmọ mi, eyi to fihan pe ṣe ni awọn ṣọja yii fiya jẹ ẹ titi to fi ku.
“Oniruuru awọn eeyan ni ṣọja to ṣiṣẹ yii ti n ran si mi lati bẹ mi, ṣugbọn ohun ti mo fẹ ni idajọ ododo, ki wọn fa ṣọja yii le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadii. Iṣẹ dila ọkọ ni ọmọ mi n ṣe, oun nikan ni ọkunrin ninu awọn ọmọ mi. Ọmọ ọdun mẹtadinlogoji ni, iyawo si ṣẹṣẹ bimọ akọbi fun un loṣu meji sẹyin ni.”

Nigba ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, n sọrọ lori ẹ, o ni loootọ ni sọja kan lọ si agọ wọn ni Ayesọ fun iranlọwọ ki oun le gbe oku kan si mọṣuari, ṣugbọn ṣe ni DPO kan ba a pe awọn oṣiṣẹ mọṣuari, ki i ṣe pe o fun un ni ọlọpaa kankan.

Leave a Reply