Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrọsheed Adewale Akanbi, ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn ajijagbara kan nilẹ Yoruba ṣe n ko ogun ja awọn Fulani darandaran kaakairi awọn ibi kan.
Oluwoo sọ pe dipo bi wọn ṣe n kogun ja awọn Fulani, iba dara ti wọn ba le kọju ija si awọn janduku ajinigbe atawọn ti wọn n gbeeyan ṣoogun, ti wọn n da ilẹ Yoruba laamu.
Ọba yii ni aimọye ẹmi lo n ṣofo nilẹ Yoruba, ti awọn oniṣẹ ibi kan n gbe ṣowo pẹlu awọn iṣẹ ibi mi-in. O ni asiko niyi fun awọn ti wọn n le awọn Fulani kiri lati koju ija wọn sawọn to n fi iwa ibajẹ da ilẹ Yoruba laamu dipo awọn Fulani darandaran. Yatọ si eyi, Ọba Abdulrasheed Adewale tun bu ẹnu atẹ lu awọn Fulani darandaran ti wọn n huwa ibajẹ ọhun loootọ.
O ni, “Asiko niyi fun awọn ọmọ Yoruba lati kọju ija sawọn ọdaran laarin wọn, dipo awọn Fulani ti wọn n le kiri. Aimọye eeyan lo ti ṣegbe danu, bi wọn ṣe n pa wọn lọmọ, bẹẹ ni wọn n gbe wọn laya ṣoogun owo ati etutu ọla. Iru awọn oniṣẹ ibi yii lo yẹ ki a le kuro, dipo ija ẹlẹyamẹya ti awọn kan ti wọn pe ara wọn ni ajijagbara Yoruba fẹẹ rawọ le bayii.”
Ọba yii sọ pe alaafia loun n wa fun ilẹ Yoruba, ati pe ija ẹlẹyamẹya ki i ṣe ohun to ba ofin Ọlọrun mu, ati pe Ọlọrun kẹyin si i paapaa.