Ẹ jawọ ninu eto idibo 2023, ẹ ṣeto ijọba fidi-hẹ foṣu mẹfa lati tun ofin ilẹ wa ṣe– Afẹ Babalọla

Faith Adebọla
Bii igba teeyan n pọn omi sinu apẹrẹ ni gbogbo isapa lati ṣeto idibo gbogbogboo lọdun 2023 yoo ja si bo ba ṣi jẹ ofin ilẹ wa tawọn ologun ṣe lọdun 1999 yii la gbara le, afi ka so eto idibo naa rọ sẹgbẹẹ kan, ki wọn ṣagbekalẹ ijọba fidi-hẹ kan ti yoo ṣe amujade ofin tuntun fun Naijiria.
Agba ọjẹ nidii iṣẹ amofin nilẹ wa, Oloye Afẹ Babalọla lo mu amọran pataki yii wa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin yii, nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn oniroyin niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti.
Amofin Agba Babalọla sọ pe ofin ti a n lo lọwọ yii ko bode mu rara, ko si le gbe Naijiria debikan, kaka bẹẹ, niṣe ni nnkan yoo maa buru si i ti a ko ba paarọ ofin naa, tori awọn aleebu rẹ kọja eyi ta a le dọgbọn si.
“Ẹ jẹ ki wọn ṣi lọọ wọgi le ọrọ eto idibo gbogbogboo 2023 na, titi ti Naijiria yoo fi ni iwe ofin tuntun to bode mu, to jẹ eyi tawọn araalu fọwọ si, ofin naa gbọdọ sọ iṣẹ aṣofin di aabọọṣẹ, ko si mu adinku ba agbara ati ipo aarẹ.
“Awọn eeyan ti wọn le wa ninu ijọba fidi-hẹ naa ni gbogbo awọn to ti jẹ aarẹ tẹlẹ ati igbakeji wọn, awọn minisita kan ati awọn gomina kan, lẹyin naa ni awọn aṣoju pataki lati origun mẹrẹẹrin Naijiria.
“Ki wọn yan aṣoju latinu ẹgbẹ awọn oniṣegun eebo, ẹgbẹ awọn amofin, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, ẹgbẹ awọn oniroyin, ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ati tawọn ajafẹtọọ gbogbo. Awọn aṣoju wọnyi ko gbọdọ fi tọrọ oṣelu ṣe.
“Ofin tuntun naa gbọdọ mu eto iṣejọba ajumọṣe laarin awọn ẹka ijọba mẹta, apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ wa, bẹẹ lo si gbọdọ ṣatunṣe si ajọṣẹ ileeṣẹ apaṣẹ, amofin ati ti idajọ. Dipo ti a oo fi maa lo eto aarẹ apaṣẹ-waa, mo dabaa ka pada si eto ki olori awọn aṣofin maa paṣẹ, ileegbimọ aṣofin apapọ kan si ti to, dipo meji.
“Ofin tuntun naa gbọdọ din owo ta a n na sori eto iṣejọba ku, tori ofin ta a n lo lọwọ yii ti sọ iṣẹ ijọba di ikoko ọbẹ fawọn to n dupo. Ofin naa tun gbọdọ faaye gba ki wọn maa ṣewadii awọn to fẹẹ dupo lati agbegbe ibilẹ, ipinlẹ ati apapọ, ki wọn ṣayẹwo orisun ọrọ wọn, ati boya wọn n jẹjọ eyikeyii lọwọ.”
Nipari ọrọ rẹ, Babalọla ni ẹnikẹni to ba fẹẹ dupo aarẹ ni Naijiria ko gbọdọ ju ọmọ ọgọta ọdun lọ, o si gbọdọ niwee-ẹri fasiti to yanran-nti.

Leave a Reply