Aderohunmu Kazeem
Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, ti bẹ gbogbo awọn ọmọ Naijiria lati yẹra fun awọn ọrọ tabi iwa to le ṣakoba fun iṣọkan ati itẹsiwaju orileeede wa.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni Aarẹ sọrọ naa lasiko to n gbe ododo eyẹ lati ranti awọn ọmọ ogun ilẹ wa to ti ku ati eto ikowojọ ti wọn ṣe fun wọn niluu Abuja.
Akọwe iroyin Aarẹ, Femi Adeṣina, to gbẹnu rẹ sọrọ sọ pe ayẹyẹ ti ọdun yii yẹ ko jẹ eyi ti yoo ran awọn ọmọ Naijiria leti lati daabo bo iṣọkan orileede yii, iṣọkan to jẹ pẹlu agbara kaka la fi ri i gba. O fi kun un pe bi a ṣe jẹ pupọ, nibẹ ni agbara wa wa.
O waa bu ọla fun awọn akọni ilẹ wa to ti lọwọ ninu ogun jija fun iṣọkan ati alaafia orileede yii.