‘Ẹ ma ma jẹ kawọn Fulani ajinigbe sọ ilẹ Yoruba dahoro’

Nigba ti wọn ji awọn eeyan gbe lọna Ibadan lọsẹ to lọ lọhun-un, ti wọn gbe Purofẹsọ yunifasiti paapaa mọ wọn, to si jẹ ni gbangba, lọwọ irọlẹ ni, gbogbo eeyan lo gba pe ọrọ awọn ajinigbe yii ti doju ẹ, koda o ti n kọja oju ẹ. Ohun ti awọn alaṣẹ ilẹ Yoruba ba fẹẹ ṣe ni ki wọn tete mọ, nitori to ba buru tan, ọrọ naa yoo le ju bi a ti ro lọ. Tabi ta lo lero pe awọn ajinigbe yoo wa niru ibẹ yẹn lati ṣe iṣẹ buruku ti wọn n ṣe, ti aya yoo ko wọn, ti wọn ko si nibẹru pe boya ẹnikẹni le mu awọn. Bi nnkan ti ri bayii, ko si tabi-ṣugbọn kan nibẹ mọ, awọn ajinigbe ti pọ ni ipinlẹ Ọyọ kaakiri, bi awọn ti wọn ji gbe si ti n royin wọn, awọn Fulani ni. Awọn Fulani ajoji ni wọn darapọ pẹlu awọn Fulani mi-in ti wọn ti paṣe ẹran dida de aarin wa, ti wọn si ti gbẹwu ọdaran wọ, lati maa ji awọn eeyan wa gbe. Awọn ti waa sọ kinni naa di kariile bayii, awọn iṣẹlẹ to si n ṣẹlẹ ni agbegbe gbogbo ni ipinlẹ naa bayii fi han pe awọn ẹni-ibi naa pọ debii pe ti awọn agbofinro ko ba tete mura gidigidi si i, lojoojumọ ni wọn yoo maa pọ si i, yoo si debi kan ti apa ijọba atawọn agbofinro ati ẹni yoowu to ba dide ko ni i ka wọn mọ. Nigba ti wọn bẹrẹ iṣẹ buruku yii nitosi Ogbomọṣọ ati agbegbe rẹ ni bii oṣu mẹta sẹyin, a pariwo nigba naa, ijọba si gbọ, wọn ni wọn yoo gbiyanju, ṣugbọn igbiyanju naa ko ti i debi to yẹ ko de, iṣẹ pọ lọwọ wọn lati ṣe gan-an. Ohun to ṣe yẹ ki gbogbo awọn agbofinro ipinlẹ Ọyọ yii pawọ-pọ lati koju awọn ajinigbe yii niyẹn, nitori ti wọn ba jọ ṣiṣẹ pọ nikan ni ogun yii le ṣẹ o. Ko dun mọọyan ninu ohun to ṣẹlẹ si ọkan ninu awọn ti wọn ji ọmọ wọn gbe lọna Ibadan yii, iyẹn Ọgbẹni Taiwo. Ọkunrin naa ni nigba ti ọrọ yii ṣẹlẹ ti oun gbọ, agọ ọlọpaa Mowe loun sare lọ, awọn ọlọpaa naa si gbowo lọwọ oun, wọn ni wọn yoo ba oun ṣe e, nigbẹyin, iwe kan ni wọn gbe le oun lọwọ pe ki oun lọ si agọ ọlọpaa ti Ọbafẹmi Owode, nigba ti oun tun debẹ, DPO to wa nibẹ ko gba lẹta lọwọ oun, iyẹn loun fi lọọ ba Amọtẹkun. Awọn Amọtẹkun adugbo naa tun ni afi ti awọn ọlọpaa Mowe ba ranṣẹ si awọn kawọn ran awọn lọwọ nikan lo ku. Ọlọpaa mi-in si pe Taiwo si kọrọ, o sọ fun un pe to ba mọ pe oun fẹẹ ri ọmọ oun laaye, ko pa ọrọ ti awọn ọlọpaa to waa ba yii ti, ko yaa lọọ wa owo ti yoo san fawọn ajinigbe. Nigba tọkunrin yii ri i pe ọlọpaa ko le gba ọmọ oun silẹ lo ba bẹrẹ si i wa owo kiri, ko too ri owo to lọọ ko fawọn yẹn, ti wọn si fi ọmọ ẹ silẹ. Ohun to tilẹ mu ibẹru wa ninu ọrọ yii ni pe lẹyin ti gbogbo ilu ti mọ ibi ti awọn ajinigbe yii wa tan, awọn ọlọpaa tabi agbofinro ko pada sibẹ lati lọọ tu wọn ka, wọn wa nibẹ pẹ titi, nitori nibẹ naa ni wọn duro si ti wọn fi gba owo lọwọ awọn eeyan awọn ti wọn ji gbe, awọn ti wọn ji gbe yii si n sọ pe oju kan naa lawọn wa, ti wọn kan n ko awọn yipo lasan. Ododo ni pe wọn yinbọn pa ọlọpaa kan, wọn si fibọn ṣe omi-in leṣe. Ohun ti gbogbo eeyan si ro pe o yẹ ko tẹle e ni ki awọn ọlọpaa ati gbogbo agbofnro to ku ṣigun lọ sibẹ, ki wọn mu ṣọja dani, ki wọn si fọ igbo naa tuu tuu. Bi eleyii ba  ṣẹlẹ, awọn ajinigbe wọnyi yoo rin jinna, wọn ko si ni i de adugbo naa mọ fun ọpọlọpọ ọjọ. Bawọn ṣọja ati ọlọpaa mi-in ko si wa, tawọn ọlọpaa Ọyọ ba ni ajọṣe to dara pẹlu awọn Amọtẹkun ati awọn fijilante, wọn le wọ inu igbẹ fun wọn, ti wọn yoo si ba wọn tu awọn ọdaran naa jade. Bi a ba ranti pe awọn Fulani to n jiiyan gbe yii, ninu wọn ti wa laarin wa tipẹ, ti wọn ti mọ gbogbo ibi ti ọna wa ninu igbo nitori wọn ti ko maaluu wọn gbabẹ tẹlẹ, ti wọn si gbọ Yoruba nitori aarin wa ni wọn n gbe, ko le ṣoro fun wọn ati awọn alejo mi-in to ba dara pọ mọ wọn lati mọ awọn ibi ti wọn yoo lo lati dena de awọn eeyan, ti wọn yoo si kọ lu wọn, ti wọn yoo ji wọn gbe, ti wọn yoo si maa gbe wọn rin inu igbo kiri. Ṣugbọn ko si bi wọn ṣe le gbọn to, tabi ki wọn mọna to, bawọn agbofinro Ọyọ ati tawọn ilẹ Yoruba to ku ba dide, ti wọn jọ ṣiṣẹ papọ, ago ni yoo ko adiyẹ wọn gbẹyin pata. Anikanrin ni i jẹ ọmọ ejo niya ni, bi ọka ba ṣaaju, ti paramọlẹ tẹ le e, ti ojola si n wọ ruru bọ lẹyin, ko sẹni kan ti yoo dabuu wọn, kaluku yoo fẹsẹ fẹ ẹ ni. Ẹyin agbofinro ilẹ Yoruba, ẹ ṣiṣẹ pọ, ẹ ma jẹ kawọn Fulani ajinigbe sọ ilẹ wa dahoro.

Leave a Reply