Wọn ran oyin sawọn ọrẹ meji to lọọ ji maaluu, nigba to fẹẹ ta wọn pa ni wọn lọọ jẹwọ f’ọlọpaa

Bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe Naijiria ni iṣẹlẹ yii ti waye, ṣugbọn ẹkọ nla ni yoo jẹ fun awọn firi nidii ọkẹ, alọ-kolohun-kigbe, awọn oloju ko-mu-o-lọ. Awọn ọrẹ meji kan ni wọn lọọ ji maaluu obinrin kan, ni wọn ba gbe e sa lọ. Niyẹn ba bẹ awọn alagbara aye lọwẹ, o ni ki wọn ba oun wa maaluu oun ti wọn ji lawaari. Nigba ti oogun abẹnu gọngọ yoo si dahun, niṣe ni oyin bẹrẹ si i ta awọn ọrẹ meji ti wọn ji maaluu yii. Ọwọ ti wọn fi fa maaluu naa ni oyin ṣuru bo, lo ba n ta wọn kikan kikan. Nigba ti wọn ko gbadun ara wọn mọ, to jẹ bi wọn jokoo, oyin yoo ta wọn, bi wọn bẹrẹ, gigan loyin n gan wọn, ni wọn kọri sagọọ ọlọpaa, wọn lọọ da maaluu ti wọn ji pada, wọn leyii ti oyin ta awọn yii ti to gẹ.

Orileede Kenya, niṣẹlẹ yii ti waye o, ni abule kan ti won n pe ni Kirinyaga, a gbọ pe gbogbo igba ni awọn ole maa waa ji awọn nnkan ọsin nibẹ.

Iru eyi naa lawọn ọmọkunrin meji kan, Phillip Wekesa, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32), ati ọrẹ rẹ, Mwamba Ili, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn. Maaluu ọmọbinrin kan ti wọn n pe ni Lillian Waithera, ni wọn lọọ ji gbe. Ni wọn ba gbe e lọ si ọja kan ti wọn n pe ni Makutano, wọn fẹẹ lọọ ta a, ṣugbọn wọn ko rẹni ra a lọwọ wọn. Ẹnu ki wọn ri eeyan ra maaluu ti wọn ji gbe yii, ki wọn da owo ẹ sapo, ni Lillian to ni maaluu fi gba agọ ọlọpaa Maputano, to wa ni Embu County, ni Kenya, lọ lọjọ kẹta, oṣu Kọkanla yii, ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Ko fi mọ ni tawọn ọlọpaa nikan. Bo ṣe kuro ni teṣan lo tun gba ọdọ babalawo kan lọ. O ni ki baba naa ba oun fi agbara oogun rẹ mu awọn to ji maaluu oun. Babalawo yii fi i lọkan balẹ pe oogun ti oun feẹ ṣe fun un yii, funra awọn to ji maaluu naa ni wọn yoo da a pada.

Ere ni awọn eeyan pe e , afi bo ṣe di ọjọ Abamẹta, Satide, iyẹn ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla yii, ti awọn ọrẹ meji yii kora wọn rẹirẹi lọ si teṣan pẹlu maaluu ti wọn ji ọhun, bẹẹ ni wọn n pariwo pẹlu bi oyin ṣe ṣuru bo wọn to n ta wọn. Ni wọn ba n ka boroboro fawọn agbofinro pe ole ni awọn o, awon lawọn ji maaluu Lillian.

Oju-ẹsẹ ni awọn ọlọpaa ranṣẹ pe obinrin naa, wọn ni ko waa wo maaluu ọhun boya eyi to n wa ni. Obinrin naa si ni bẹẹ ni, maaluu oun ti wọn ji toun n wa naa ni.

Afigba ti wọn pe babalawo to ran oyin si awọn eeyan naa de teṣan ọlọpaa o, wọn ni ko waa mu ohun to fi ran oyin si awọn eeyan naa kuro. Iyalẹnu lo si jẹ fun gbogbo awọn to wa nibẹ nigba ti baba naa sọrọ wuyẹwuyẹ, to si da gbogbo oyin to wa lọwọ wọn naa pada sinu apo rẹ, lo ba kuro lagọọ ọlọpaa, o ba tirẹ lọ.

Tiyanu tiyanu ni gbogbo awọn to wa ni teṣan naa fi n wo baba to waa fi majiiki ko oyin kuro lọwọ awọn ole to ji maaluu naa.

Ṣugbọn ẹni to jẹ bii baalẹ adugbo naa ti rọ awọn ara abule yii ki wọn yee fi oogun wa nnkan wọn to ba sọnu,

Leave a Reply