Ẹ takete si aṣilo oogun, Gomina Abdulrazaq rọ awọn ọdọ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, darapọ mọ ọgọọrọ awọn eeyan lagbaye lati ṣami ayẹyẹ gbigbogun ti aṣilo oogun ati ṣiṣe fayawọ egboogi loro, o rọ awọn ọdọ ki wọn takete si asiko oogun.
Gomina Abdulrazaq ati ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun ati ṣiṣe fayawọ egboogi oloro nilẹ yii (NDLEA), ẹka tipinlẹ Kwara, ni wọn ṣe agbekalẹ eto kan niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, lati fi ṣami ayẹyẹ gbigbogun ti aṣilo oogun ati egboogi oloro ti ọdun 2022, nibi ti wọn ti ṣalaye lẹkun-un-rẹrẹ lori akoba ti aṣilo oogun n ṣe fun ilera ọmọniyan.

Abdulrazaq, gboriyin fun ajọ NDLEA, ti ẹka ipinlẹ Kwara, ati tijọba apapọ, fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lori ṣiṣe ipolongo ta ko aṣilo oogun fawọn araalu, o jẹẹjẹẹ lati maa tẹsiwaju nipa ṣiṣe atilẹyin fun ajọ naa, ki ki iwa buruku naa le dinku lawujọ. Bakan naa ni gomina tun dupẹ lọwọ awọn ọba alaye fun bi wọn o ṣe gba iwa ọdaran laaye lawọn agbegbe wọn, o rọ awọn ọdọ ki wọn takete si aṣilo oogun ati egboogi oloro, ki wọn le ni ọjọ ọla rere.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: