Ẹ wo Ṣẹgun to fipa ba ọmọ ọdun mejila lo pọ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ẹsọ alaabo (NSCDC) ti fi panpẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) kan, Ṣẹgun Oni, fẹsun pe o n fi tipatipa ba ọmọdebinrin ti ko ju ọdun mejila lọ, Ajibade Aminat, lopọ, niluu Igbaja, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, n ipinlẹ Kwara.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ẹsọ alaabo (NSCDC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, fi sita, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni baba to bi baba Aminat mu ẹsun wa si ọfiisi awọn to wa niluu Igbaja pe, ọkunrin kan to n jẹ Sẹgun n fi tipatipa ba Aminat lo pọ labẹ igi mangoro, oun si ka wọn mọ.

Afọlabi tẹsiwaju pe ọmọbinrin naa ni ipenija ọrọ ṣiṣọ, to jẹ pe awọn eeyan ki i gbọ ohun to n wi daadaa, ati pe nigba ti wọn gbe ọmọ naa de ileewosan, ti wọn ṣe ayẹwo, ni wọn ri okodoro pe loootọ lo ba a ni nnkan pọ.

O fi kun un pe nigba ti awọn mu Ṣẹgun fun lati fọrọ wa a lẹnu wo, o ni lootọ loun maa n ba ọmọ naa lo pọ, ati pe ẹbun kekere loun fi maa n tan an lọ si kọrọ, to oun yoo si lo anfaani ẹbun ti oun fun un lati ba a lopọ.

Afọlabi ti waa sọ pe, lẹyin ti awọn ba pari iwadii, afurasi yii yoo foju ba ile-ẹjọ.

 

Leave a Reply

//outrotomr.com/4/4998019
%d bloggers like this: